Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ti fi panpẹ ofin gbe awọn gende meji kan, Ọlasunkanmi Ọlarewaju, aka Abọrẹ, ati Adeniyi Juwọn aka Jboy, ti wọn si ti wọ wọn lọ sile-ẹjọ Majisireeti to fikalẹ siluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn ṣeku pa ẹni kẹta wọn, Abiọdun Oyinloye.
Awọn agbofinro ṣalaye pe lọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹrin, ọdun 2023 yii, ni awọn afurasi mejeeji yii ṣeku pa Abiọdun, wọn lo ji ẹgbẹrun lọna marunlelọgọta Naira (65,000) awọn.
Awọn afurasi mejeeji jẹwọ pe loootọ lawọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn, ati pe Oyinloye, iyẹn oloogbe ji owo awọn gbe lawọn ṣe lu u lalubami, to si gbabẹ ku.
Agbefọba, Gbenga Ayẹni, rọ ile-ẹjọ ko fi awọn afurasi naa sahaamọ titi ti iwadii yoo fi pari lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan wọn.
Onidaajọ M. O. Abayọmi, gba ẹbẹ agbefọba wọle, o paṣẹ pe ki wọn sọ awọn mejeeji sọgba ẹwọn. Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ si ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii.