Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kejila yii, ni awọn ọrẹ meji kan, Emeka Celestine ati ThankGod Madu, gbadajọ ẹwọn ọdun mọkanlelogun ẹnikọọkan nile-ẹjọ giga to wa l’Abẹokuta. Ẹsun idigunjale ni wọn ni wọn jẹbi ẹ.
Adajọ Patricia Oduniyi to gbe idajọ naa kalẹ ṣalaye pe gbogbo ẹri lo foju han pe awọn olujẹjọ meji yii jẹbi ẹsun idigunjale, wọn si gbọdọ faṣọ penpe roko ọba fọdun mọkanlelogun, lai si aaye owo itanran kankan.
Ṣaaju ni Agbefọba T.O Adeyẹmi, ti ṣalaye fun kootu pe lọjọ kọkandinlogun, oṣu keji, ọdun 2015, ni Emeka ati ThankGod pẹlu awọn yooku wọn to ti sa lọ bayii digunjale nikorita Ṣiun, loju ọna to lọ si Abẹokuta.
O tẹsiwaju pe loju ọna naa ni wọn ti yọ nnkan ija oloro si Ọgbẹni Ṣẹgun Owoẹyẹ, wọn gba ẹgbẹrun mẹrindinlogoji naira ( 36,000) lọwọ rẹ, wọn tun gba foonu rẹ.
Bakan naa lo ni wọn digun gba ẹgbẹrun lọna igba naira ( 200,000) lọwọ Ọgbẹni Ogunjimi Taiwo, wọn gba foonu ẹ pẹlu, ki wọn too waa gba ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira(120,000) lọwọ ọkunrin kan torukọ ẹ n jẹ Surajudeen Kọdaolu. Agbefọba sọ pe wọn gba awọn nnkan ẹṣọ lọwọ Ọgbẹni Kọdaolu yii, wọn si gba kaadi ATM rẹ pẹlu.
Awọn iwa ti wọn hu yii ta ko abala to n ri si gbigbe nnkan ija oloro kiri, eyi tijọba apapọ Naijiria n ri si, ti ijiya si wa fẹni to ba lukun ofin naa.
Bo si tilẹ jẹ pe ọdun kẹfa ree ti ẹjọ yii ti wa nilẹ, ti wọn ti n gbọ ọ lọ siwaju lọ sẹyin, l’Ọjọbọ to kọja yii, Adajọ Patricia Oduniyi yanju ẹ, o paṣẹ ẹwọn ọdun mọkandinlogun fun ẹnikọọkan awọn olujẹjọ yii, o ni ko saaye owo itanran, afẹwọn ọlọdun gbọọrọ.