Ọrẹ mẹta yii ṣa ọlọkada pa, lasiko ti wọn fẹẹ maa gbe kẹkẹ naa sa lọ ni wọn mu wọn

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ọmọ Hausa mẹta lọwọ awọn araalu tẹ nibi ti wọn ti n digunjale lagbegbe Sango, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, lọsẹ to kọja.

Awọn afurasi ọdaran ọhun, Isah Umoru, ẹni ọdun marundinlọgbọn, Iliasu Ibrahim, ọmọ ọdun mejilelogoji ati Muhammad Bakare to ti to bii ọmọ ọgbọn ọdun, lọwọ tẹ lẹyin ti wọn pa ọlọkada kan nipakupa lagbegbe naa.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu ọlọpaa kan to ba wa sọrọ ni bonkẹlẹ lori iṣẹlẹ ọhun pe ko din lawọn ọlọkada bii marun-un lagbegbe Sango ti wọn ti ba iku ojiji pade lati ọwọ Umoru atawọn ikọ rẹ.

O ni ṣe ni wọn maa n tan awọn ọlọkada naa lọ si kọrọ kan, nibi tawọn eeyan ko fi bẹẹ si, nibẹ ni wọn yoo lu onitọhun pa si ki wọn too gbe ọkada rẹ sa lọ.

O ni lọjọ tọwọ awọn ogbontarigi adigunjale naa pada ṣegi, ọkunrin ọlọkada kan ni wọn tun tan lọ si agbegbe ọhun gẹgẹ bii ìṣe wọn, bi wọn ṣe pa ọlọkada naa tan ti wọn fẹẹ maa gbe ọkada rẹ sa lọ lawọn eeyan kan ṣuru bo wọn, ti wọn si mu wọn.

ALAROYE gbọ pe awọn ọdọ agbegbe naa gbiyanju ati dana sun awọn ọdaran mẹtẹẹta ṣugbọn ti Baálẹ̀ ilu naa ko gba fun wọn, oun lo sare  pe awọn ọlọpaa ki wọn le tete waa da si ọrọ naa. Iṣẹlẹ yii lo bi awọn ọdọ kan ninu ti wọn fi ṣe ikọlu si Baálẹ̀, ninu eyi ti wọn ti ba ọkọ ayọkẹlẹ rẹ jẹ.

Ninu ọrọ soki ti Umoru ba wa sọ lasiko ti wọn n ṣe afihan oun atawọn ikọ rẹ lọdọ awọn ọlọpaa to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, o ni ipinlẹ Kebbi loun ti wa.

Umoru ni ibi ti oun ti n ṣiṣẹ atunbata-ṣe ti oun yan laayo ni Iliasu ati Muhammad ti waa bẹ oun lati fi ọkada gbe awọn lọ sibi kan.

O ni bi awọn ṣe de agbegbe Sango, lawọn ba ọlọkada kan to ti n duro de awọn nibẹ, Umoru ni oun ko ti i duro tan ti ọkan ninu awọn ti oun gbe sẹyin fi bẹ silẹ, to si la igi mọ ọkunrin ọlọkada naa lori, to si ṣe bẹẹ ku loju-ẹsẹ.

O ni ọpẹlọpẹ awọn eeyan kan lagbegbe naa atawọn ọlọpaa ti wọn de lasiko ni ori fi ko oun yọ lọwọ awọn to fẹẹ dana sun awọn lọjọ naa.

Leave a Reply