Ori ade sunta: Ọba alaye atawọn ijoye rẹ dero ọgba ẹwọn Abolongo, l’Ọyọọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọrọ tawọn eeyan maa n sọ pe ori ade ki i sunta ko ri bẹẹ mọ bayii, ki i ṣe ita nikan lori ade n sun bayii, koda, odidi ọba ti n sun ọgba ẹwọn bayii.

Lati Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii,  ni Ori-ade kan, Ọba Solomon Akinọla, Oloko tilu Oko, nipinlẹ Ọyọ, pẹlu meji ninu awọn ijoye rẹ ti n sun inu ahamọ ọgba ẹwọn bayii, ibẹ ni wọn yoo si wa titi d’ọjọ Aje, Mọnde ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu yii.

Ọba Akinọla, ijoye rẹ meji, atawọn mejila mi-in ni wọn dero ahamọ ọgba ẹwọn to wa l’Abolongo, niluu Ọyọ, nitori ẹsun ọdaran ti wọn fi kan wọn ni kootu. Wọn ni wọn gbé igbesẹ lati paayan nitori ija ilẹ, ati pe bi wọn ṣe n ja si ilẹ onilẹ ni wọn n ṣe awọn eeyan leṣe.

ALAROYE gbọ pe ọpọ igba ni kabiesi yii ti ran awọn ẹruuku lọọ ka awọn eeyan mọ ori ilẹ ti wọn n kọle le lori lọwọ, ti awọn alailaaanu ẹda ti wọn ba ran lọ yii yoo si lu awọn eeyan bii ejo aijẹ, lai bikita bi wọn ba le ku.

Eyi ti wọn ṣe laipẹ yii lo bu wọn lọwọ, nigba ti wọn lọọ ka ọkunrin ọmọwe kan, Dokita Isaac Abiọdun, mọ ori ilẹ to n kọle le lori lọwọ laduugbo kan ti wọn n pe ni Aagba, niluu Ogbomọṣọ.

Alubami ni wọn lu Dokita Abiọdun atawọn lebira to n ba a ṣiṣẹ lori ilẹ ọhun, ti ọkunrin alakọwe naa si lọọ fi ẹjọ wọn sun awọn agbofinro lẹyin to jajabọ lọwọ wọn.

Orukọ awọn ijoye ti ọwọ awọn ọlọpaa ba pẹlu Ọba Akinọla ni Oloye Sunday Aderinto ati Jimoh Asimiyu.

Awọn mejila yooku ni Timothy Aderintọ, Matthew Akintarọ, Rafiu Ganiu, Adejare Adeleru, Samson Ogunmọla, Zachiaus Adeleru, Kamorudeen Ajibade, Raji Rasaq, Mutiu Arowoṣaye, Oyeyẹmi Oyelekan, Oluṣẹgun Oyelekan, ati Sheriff Adio.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii, lọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ gbe awọn olujẹjọ mẹrẹẹrinla lọ sile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Ogbomọṣọ, fun ẹsun ìjìjàgbalẹ̀, iwa idaluru ati gbigbero lati paayan.

Ọba Akinọla atawọn olujẹjọ mẹrinla yooku sọ pe awọn ko jẹbi awọn ẹsun naa. Lẹyin naa l’Onidaajọ K.A. Adedokun sun igbẹjọ ọhun si ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu yii, to si paṣẹ pe ki wọn fi awọn olujẹjọ maa pamọ si ahamọ ọgba ẹwọn Abolongo, to wa niluu Ọyọ, titi dọjọ ti igbẹjọ ọhun yoo maa tẹsiwaju.

Leave a Reply