Ọlawale Ajao
Niṣe ni ọpọ awọn to wa nibi ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti ṣafihan awọn ọdaran mẹrindinlogun kan kawọ mọri nigba ti wọn ri ori eeyan ti wọn le jọ bii iṣu, ifun, ọkan, atawọn ẹya ara eeyan mi-in ti wọn ṣẹṣẹ pa ti wọn ba lọwọ awọn eeyan yii.
Awọn afeeyan ṣowo mẹrindinlogun ọhun lọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ tẹ pẹlu ori eeyan gbigbẹ mẹsan-an, atawọn ẹya ara eeyan mi-in bii ifun, ẹdọ, ọkan ati bẹẹ bẹẹ lọ ti wọn ba lọwọ wọn ni Orita Aperin, to wa nijọba ibilẹ Ọna Ara, niluu Ibadan, nipinlẹ Oyọ.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keji, oṣu Kẹta, ọdun yii, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Adebọwale Williams, ṣafihan awọn ọdaran yii nipasẹ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Adewale Oṣifẹsọ, ẹni to ṣalaye pe ki i ṣe oju kan naa lawọn ti mu awọn eeyan ọhun, o ni kaakiri agbegbe ilu Ibadan lawọn ti ṣa wọn.
Oṣifẹsọ ni iṣẹ ti awọn eeyan naa yan laayo ni tita ori ati ẹya ara eeyan kaakiri ipinlẹ Ọyọ atawọn ibomi-in.
Nigba to n ṣalaye bọwọ ṣe tẹ wọn, Oṣifẹsọ ni, ‘‘Lọjọ kejilelogun, oṣu Keji yii, ni aṣiri tu si awọn ikọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wọn wa ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ pe awọn ọdaran kan wa nibi kan ti wọn ko ni iṣẹ mi-in ti wọn n ṣe ju ki wọn maa ta ori atawọn ẹya ara eeyan mi-in fun awọn to n ṣe etutu ọla kaakiri ilu Ibadan, nipinlẹ Ọyọ.
‘‘Eyi lo mu ki awọn ikọ ọlọpaa to maa n tọpinpin iwa ọdaran yii lọọ ka awọn olubi ẹda naa mọ ibuba wọn ni adugbo Orita Aperin, niluu Ibadan. Nibẹ lọwọ wọn si ti tẹ mọkanla ninu wọn. Ori eeyan to ti gbẹ mẹsan-an ati ori tutu kan ti ẹjẹ ṣi wa lara rẹ, pẹlu ifun eeyan ti wọn ṣẹṣẹ pa ati oriṣiiriṣii awọn ẹya ara mi-in bii kindinrin, ọkan ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ka mọ wọn lọwọ.
‘‘Nigba ti wọn n ṣalaye bi wọn ṣe ri awọn ohun ti wọn ka mọ wọn lọwọ naa, awọn ọdaran naa jẹwọ pe loootọ lawọn ṣẹ si ofin pẹlu ẹya ara eeyan ti wọn ba lọwọ awọn. Wọn ni awọn itẹkuu kaakiri lawọn ti maa n hu ori gbigbẹ. Ibẹ naa lawọn si ti hu eyi to wa lọwọ awọn yii. Nigba ti wọn n ṣalaye ibi ti wọn ti ri ori tutu ati ẹya ara eeyan tutu to wa lọwọ wọn, wọn ni ẹni kan tawọn jọ n ṣiṣẹ, ṣugbọn to ti sa lọ bayii lo maa n pa awọn eeyan naa, ti yoo si ko ẹya ara eeyan tutu naa fun awọn lẹyin to ba ti pa awọn eeyan tọwọ rẹ ba tẹ tan.
Oṣifẹsọ ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lati mu awọn yooku wọn to ti sa lọ bayii.