Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Bi ki i baa ṣe ti awọn oṣiṣẹ alaabo ti wọn ko gbọjẹgẹ, orin mi-in ni awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun iba maa kọ bayii pẹlu bi awọn agbanipa ṣe ya bo ile Olori ileegbimọ aṣofin Ọṣun, Ọnarebu Timothy Owoẹyẹ, nidaaji Ọjọruu, Wẹsidee, tibọntibọn.
Lati nnkan bii ọsẹ meji sẹyin ni oniruuru iṣẹlẹ iṣekupani ti n ṣẹlẹ niluu Ileṣa, ti awọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji; PDP ati APC, si n naka aleebu siraa wọn.
O kere tan, eeyan mẹwaa lo ti ba wahala naa lọ labala mejeeji, bẹẹ ni ọkẹ aimọye dukia awọn araalu ti ṣofo, eyi jẹ ọkan lara idi ti awọn ọmọ ẹgbẹ APC ṣe pariwo lọsẹ to kọja pe ki ọga agba ọlọpaa patapata lorileede yii gbe kọmiṣanna ọlọpaa Ọṣun kuro, wọn ni agbara rẹ ko ka wahala oṣelu to n lọ lọwọ l’Ọṣun.
Ṣugbọn ọrọ tun gba ibomi-in yọ nidaaji ọjọ Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Keji, ọdun yii, nigba ti awọn agbanipa naa ya wọ ile Ọnarebu Owoẹyẹ, ti wọn si ṣina ibọn bolẹ lati le awọn oṣiṣẹ alaabo ti wọn wa nibẹ lugbẹ lati le ṣiṣẹ ọwọ wọn.
Ninu ọrọ Owoẹyẹ, o ni Ọlọrun nikan lo ṣaanu oun, nitori ohun ti awọn eeyan naa ro kọ ni wọn ba pẹlu bi awọn oṣiṣẹ alaabo ti wọn wa nile oun ṣe doju ija kọ wọn titi ti wọn fi sa lọ.
Owoẹyẹ ṣalaye pe o jẹ iyalẹnu fun oun pe iru igbesi-aye ainifọkanbalẹ bẹẹ le tete pada sipinlẹ Ọṣun lai ti i pe oṣu mẹta ti ẹgbẹ PDP gbajọba.
O ni eeyan maru- un to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni awọn janduuku oloṣelu pa nipakupa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lagbegbe Eti-Ọọni, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Atakumọsa, Oke Aga, niluu Ileṣa.
O waa ke si ileeṣẹ ọlọpaa lati dide si ojuṣe wọn lasiko yii, ki nnkan too bọ sori.
Ṣugbọn agbẹnusọ lori eto iroyin fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọlabamiji Ọladele, sọ pe ko si ootọ ninu nnkan ti Owoẹyẹ sọ, o ni ki olori awọn aṣofin naa bomi suuru mu, ko si lo ipo rẹ lati ṣeto alaafia nilẹ Ijeṣa.
O ni ko sẹni ti ko mọ pe Gomina Ademọla Adeleke ko fẹran jagidijagan rara, ko si le lọwọ si i nibikibi. O ni ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP mẹta ni wọn pa nipakupa lọjọ Iṣegun, Tusidee, niluu Ileṣa yii kan naa.