Ori ko ọmọ ọdun mẹrinla yọ lọwọ awọn ajinigbe l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọmọdekunrin kan ti ko ti i ju ẹni ọdun mẹrinla lọ, Ayọmide Ogunjolu, lori ko yọ lọwọ awọn to ji i gbe l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

ALAROYE gbọ pe ni agbegbe aafin Ọjọmu, niluu Ọwọ, nijọba ibilẹ Ọwọ, lawọn oniṣẹẹbi naa ti ji Ayọmide gbe lọsan-an yii, ki Ọlọrun too ko ọmọ naa yọ lọwọ wọn niluu Ondo, lọjọ yii kan naa.

Alaye ti Ayọmide ṣe fawọn oniroyin kan to ri i lẹyin ti ori ko o yọ ni pe ọṣẹ ifọyin ni baba oun ran oun lati lọọ ra wa lọsan-an ọjọ naa, boun ṣe n pada bọ loun pade awọn ọkunrin kan, ni wọn ba paṣẹ foun lati tẹle awọn.

O ni oun kọkọ fẹẹ ṣagidi, ṣugbọn awọn ọkunrin naa tete kilọ foun lati ma ṣe gbiyanju ati jampata, nitori ti oun ba kọ lati tẹle aṣẹ ti awọn pa, awọn yoo yinbọ pa oun.

Pẹlu ibẹru ni Ayọmide ni oun fi tẹle wọn, ti wọn si wọ oun ju sinu ọkọ. Ọmọdekunrin yii ni ẹkun loun n wa mu bii gaari ni gbogbo igba ti wọn fi n gbe oun kọja ilu Akurẹ, Ondo, titi ti awọn fi de Ọrẹ.

Aarọ ọjọ keji, Ọjọbọ, Tọsidee, lo ni wọn tun gbe oun pada siluu Ondo lati Ọrẹ, ti wọn saa n wa ọkọ kiri awọn adugbo kan.

Inu ọkọ yii lo ni oun wa pẹlu wọn laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ti oun fi n gbọ ariwo fere ya-fun-un awọn ọlọpaa, o ni kiakia loun bẹrẹ si i pariwo, ‘ẹ gba mi o’ leyii to mu ki ẹru nla ba awọn ajinigbe ọhun, ti wọn si sare ti oun jade ninu ọkọ wọn, ki wọn too sa lọ.

Ọmọkunrin ọhun ni lẹyin ti oun jajabọ lọwọ wọn tan loun beere ibi ti oun wa lọwọ awọn eeyan, ti wọn si jẹ ko ye oun pe adugbo Akinjagunla, niluu Ondo, nibi ti wọn ja oun si.

Lẹyin-o-rẹyin lo ni oun pe baba oun sori aago lati ṣalaye oun to sẹlẹ fun un.

Awọn araadugbo naa ni wọn ransẹ pe ẹṣọ Amọtẹkun, ẹka tilu Ondo, ti wọn si fa ọmọkunrin ọhun le wọn lọwọ.

Leave a Reply