Monisọla Saka
Pẹlu bi Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe n palẹmọ lati gbe ijọba ọdun mẹjọ rẹ silẹ, ti ọjọ ti yoo lo nipo aṣẹ naa si ti din ni ọsẹ kan, o ti n da ara ẹ lọkan le pe aki i ṣee mọ, ti wahala kankan ba fẹẹ bẹ silẹ, tabi ti ẹnikẹni ba fẹẹ gbogun ti oun, oun ti pọnmi silẹ de oungbẹ, bẹẹ loun ti dami siwaju lọdọ awọn orilẹ-ede Niger Republic, dandan ni ki oun tẹlẹ tutu. Buhari ni oun ti ṣiṣẹ lori ajọṣepọ to dan mọran pẹlu awọn orilẹ-ede alamuuleti, ati pe tẹnikẹni ba fẹẹ kọju ija soun, awọn eeyan oun nilẹ Niger, yoo gbe oun nija.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Aarẹ sọrọ yii nibi ti wọn ti n ṣi olu ileeṣẹ ajọ aṣọbode ilẹ wa, eyi ti wọn fi owo to le ni biliọnu mọkandinlogun Naira o le diẹ (19.6 billion), pari ẹ niluu Abuja.
O ni, “Mo ṣeto lati wa gbogbo ọna ti ma a fi jinna siluu Abuja. Mo wa lati adugbo to jẹ pe o jinna si Abuja gidi tẹlẹtẹlẹ naa. Tẹnikẹni ba waa gbe ọwọkọwọ, ajọṣepọ to duroore wa laarin emi atawọn orile-ede to mule ti wa, awọn eeyan Niger Republic yoo gbeja mi”.
O ni bo tilẹ jẹ pe yoo wu oun lati dari pada siluu abinibi oun, iyẹn Daura, nipinlẹ Katsina, ṣugbọn ifọkanbalẹ wa founpe gbagbaagba lawọn ara Niger yoo ti oun leyin.