Orileede Brazil ni ọmọ Naijiria yii ti n gbe kokeeni bọ ti wọn fi mu un n’Ikẹja

Adewale adeoye

Ọdọ ajọ to n gbogun ti gbigbe ati lilo egboogi oloro lorileede yii, ‘National Drug Law Enforcement Agency’ (NDLEA), ẹka tipinlẹ Eko, ni afurasi ọdaran kan, Ọgbẹni Eseokoli, ẹni ọdun mọkandinlọgọta, wa bayii. O n ran awọn agbofinro lọwọ ninu iwadii wọn lori ẹsun pe o gbe egboogi oloro, iyẹn kokeeni wọlu Eko lati orileede Brazil. Inu ikun rẹ lo tọju ọpọlọpọ kinni naa si.

ALAROYE gbọ pe ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni ọwọ awọn oṣiṣẹ  NDLEA tẹ gbajumọ oniṣowo egboogi oloro ọhun ni papakọ ofurufu ‘Murtala Muhammed International Airport, to wa niluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, lẹyin to bọ silẹ ninu ọkọ baaluu Ethiopian Airlines, kan to gbe e de si Naijiria.

Lati ilu Sao Paulo, lorileede Brazil, ni afurasi ọdaran naa ti n bọ, ọpọlọpọ kokeeni lo si fẹẹ dọgbọn gbe wọlu Eko kọwọ too tẹ ẹ.

Alukoro eto iroyin ajọ naa, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kin-in-ni, oṣu Kejila, ọdun yii, sọ pe ni Murtala Muhammed International Airport, l’Ekoo, lọwọ ti tẹ ẹ.

O ni nigba ti wọn fura si irin ẹsẹ rẹ ni wọn da a duro, ti wọn si ṣayẹwo finnifinni si ara rẹ. Nibẹ ni ẹrọ aṣofofo ti wọn n lo ti fi han pe ẹru ofin wa ninu ọmọkunrin naa.

Nigba to n ṣalaye nipa bi ọwọ ṣe tẹ Eseokoli ninu atẹjade to fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun, Bababfẹmi ni, ‘‘Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, ni afurasi ọdaran naa to jẹ oniṣowo egboogi oloro gbe kokeeni wọlu Eko wa. Inu ikun rẹ lo tọju ẹru ofin naa si. Lasiko to fẹẹ kuro ni papakọ ofurufu naa la fura si i pe nnkan wa lara rẹ, a fun un ni nnkan mu, o si bẹrẹ si i ya awọn kokeeni to di kulubọ-kulubọ mọ igbọnsẹ rẹ. Iwadii ta a ṣe fi han pe lati ilu Sao Paulo, lorileede Brazil, ni ọkọ baaluu Ethiopian Airlines, to ba de ti n bọ. O si ti pẹ to ti n ṣowo egboogi oloro naa.

Alukoro ni awọn maa too foju rẹ bale-ẹjọ, lẹyin tawọn ba pari iwadii nipa rẹ.

Leave a Reply