Faith Adebọla, Eko
Bi gbogbo aye ṣe n dagbere irinajo ilẹ okeere fawọn eeyan wọn naa lobinrin yii, Abilekọ Chinyere Nora Nnadi, ṣe dagbere, afi bi aṣiri ṣe tu pe egboogi oloro lo fẹẹ gbe sọda siluu oyinbo, ọgọrun-un lailọọnu egboogi heroin ti wọn di kulube kulube ni wọn ka mọ ọn lọwọ ni papakọ ofurufu.
Alamoojuto lẹka iroyin tileeṣẹ NDLEA, iyẹn ajọ to n gbogun ti okoowo ati ilo egboogi oloro nilẹ wa (Nigeria Drug Law Enforcement Agency), Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi lo sọrọ yii ninu atẹjade to fi lede fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sunday yii, lori iṣẹlẹ ọhun.
O ni baaluu Qatar Airways to fẹẹ gbera lati Naijiria lọ siluu Florentina, lorileede Italy, lọjọ Ẹti, Furaidee, to lọ yii, lobinrin naa fẹẹ wọ, o si ti gba gbogbo iwe, o ti kọja lẹnu ọna ayewo pẹlu, ṣugbọn ẹru rẹ ni ko ṣee ṣe fun lati kọja, latari bi ẹrọ to n ṣofofo ẹru ofin ni papakọ ofurufu Muritala Mohammed, n’Ikẹja, ipinlẹ Eko, ṣe n han gan-an-rangan, lati fihan pe obinrin naa lẹbọ lẹru.
Nigba ti wọn tuṣu desalẹ ikoko awọn ẹru ọhun, aṣiri tu pe awọn ike ti afurasi ọdaran yii ko jọ ti wọn rọ kiriimu ipari-parun (hair cream) si, egoogi oloro ti wọn we sinu lailọọnu ni wọn fi tẹlẹ awọn ike naa ki wọn too da kiriimu sori wọn.
Lẹyin ayẹwo, ọgọrun-un ni lailọọnu egboogi ni wọn ri ninu ike kiriimu marun-un to di i si, lobinrin naa ba jẹwọ pe oniṣowo egboogi oloro loun.
Bakan naa, bi Babafẹmi ṣe wi, o lawọn oṣiṣẹ NDLEA tun ri ẹru egboogi oloro ti wọn di saarin awọn eroja iṣaraloge ti wọn fẹẹ gbe lọ sorileede Britain, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejila, oṣu kẹjọ yii.
Nigba ti wọn ṣewadii, egboogi oloro heroin to wa ninu ẹru ọhun wọn kilo mẹtadinlaaadọrin (66.6 kg), kilo aadọrin ni ti kokeeni, igbo naa si wa nibẹ pẹlu.
Iwadii ṣi n lọ lọwọ lori ẹni to gbe ẹru yii wa, to fẹẹ fi i ranṣẹ, bẹẹ ni iwadii to lọọrin ti bẹrẹ lori Chiyere tọwọ ṣẹṣẹ ba.