Faith Adebọla, Eko
Pẹlu bi ariwo ipe fun idasilẹ orileede Oduduwa ṣe n roke si i nilẹ Yoruba, ati bi iṣoro eto aabo to mẹhẹ ṣe n gbilẹ si i, awọn gomina ilẹ Yoruba yoo ṣe ipade apero nla kan pẹlu Aṣiwaju Bọla Tinubu ati olori awọn aṣoju-ṣofin, Fẹmi Gbajabiamila, lati fori Ikooko ṣọọdun lori ọrọ ọhun.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Oloye Bisi Akande to ti figba kan jẹ alagba ẹgbẹ oṣelu APC ati gomina ipinlẹ Ọṣun lo ṣeto ipade nla ọhun.
Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtalelogun, ọsu karun-un, nipade naa maa waye nile ijọba ipinlẹ Eko to wa ni Marina, l’Erekuṣu Eko. Aago meji ọsan ni wọn nipade naa maa bẹrẹ.
Lara awọn ti wọn ti kọwe pe lati pesẹ sipade naa ni awọn gomina ipinlẹ Ogun, Eko, Ọṣun, Ondo ati Ekiti.
Bakan naa ni awọn eekan eekan nilẹ Yoruba ati alẹnulọrọ lagbo oṣelu wa lara awọn ti wọn n reti nipade naa. Lara wọn ni Oloye Ṣegun Ọṣọba, Ajagun-fẹyinti Alani Akinrinade, Alagba Pius Akinyẹlurẹ, Ọtunba Niyi Adebayọ ati awọn mi-in.
Atẹjade kan ti wọn fi lede lori apero ọhun sọ pe koko pataki ti wọn yoo jiroro nipade naa da lori ọrọ idasilẹ Orileede Oduduwa, eto aabo to mẹhẹ, ati bi ipo oṣelu ṣe ri lorileede wa lasiko yii.