Aderohunmu Kazeem
Ileeṣẹ LCC, iyẹn ileeṣẹ to n mojuto too geeti Lẹkki, nibi ti wahala ti ṣẹlẹ nijọsi, ti sọ pe kamẹra fidio aṣiri ti wọn maa n gbe si awọn ibi kọlọfin lati mọ awọn ohun to n lọ tabi ohun to ba ṣẹlẹ ko ṣiṣẹ lasiko iṣẹlẹ Lẹkki, nibi tawọn ọlọpaa ti yinbọn mọ awọn oluwọde logunjọ, oṣu kewaa, ọdun yii.
Nigba ti wọn n ṣalaye niwaju igbimọ oluwadii, Ọga agba ileesẹ naa, Abayọmi Ọmọmuwa sọ pe fun igboke gbodo ọkọ ni kamẹra aṣiri naa wa fun, ki i ṣe fun eeyan rara.
Niwaju agbejọro ijọba, Abiọdun Owonikoko (SAN), lo ti sọrọ naa lasiko iwadii awọn igbimọ ti wọn gbe kalẹ lati wadii iṣẹlẹ to ṣẹlẹ ni Lẹkki yii ati ifiyajẹni awọn SARS ni ọjọ Isegun, ọsẹ yii.
O ni kamẹra to le rin ni iwọn kilomita meji yii ṣiṣẹ titi di aago mejọ alẹ ọjọ iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ni deedee aago mẹjọ alẹ naa lo deede daṣẹ silẹ. Eyi ko si ṣẹyin ina to jo nibẹ to jo awọn waya kan.
Ọkunrin naa sọ niwaju igbimọ yii pe, ‘‘Ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ogunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii, la ṣadeede ri i pe awọn kan n kora wọn jọ sitosi ile itaja kan to wa nitosi too geeti yii. A si pinnu lati daabo bo awọn ohun eelo ti a n lo nibẹ nitori pe wọn wọn lowo gidigidi. A yọ irinṣẹ to maa n ṣafihan nọmba awọn mọto atawọn irinṣẹ olowo iyebiye mi-in, ṣugbọn a ko fọwọ kan ẹrọ ayaworan ikọkọ yii.
‘‘Afi bo ṣe di bii deede aago mẹjọ alẹ ti kinni naa ko ṣiṣẹ mọ nitori idiwọ oju opo to ni nitori bi ina ṣe ti jo ẹrọ alatagba to yẹ ko mu ina lọ sibẹ.
‘‘Awọn oṣiṣẹ wa kankan ko si nibẹ lasiko ti wọn n yinbọn yii nitori pe a ti ni ki wọn maa lọ sile nitori ofin konilegbele tijọba ipinlẹ Eko ni yoo bẹrẹ laago mẹrin irọlẹ.
Awọn kan n sọ pe awa la pana, awa kọ la pana, a si ti gbe atẹjade kan jade lati sọ pe eleyii ko ri bẹẹ, bakan naa ni a ko gba aṣẹ kankan lati ọdọ ijọba ipinlẹ Eko tabi ileeṣẹ ologun pe ki a pana naa. Awa kan kuro ni agbegbe yii ni igbọran si aṣẹ ijọba pe konilegbele yoo berẹ laago mẹrin alẹ ni.’’
O fi kun un pe awọn ko ti i le debi iṣẹlẹ naa latọjọ to ti ṣẹlẹ afigba ti awọn igbimọ yii wa sibe. O ni gbogbo ileesẹ yii lo jo kanle, yoo si gba awọn ni oṣu mẹfa lati tun un ṣe.