Ọrọ ebi yii ti n kọja afarada o- Abdulsalami Abubakar

Adewale Adeoye

Olori orileede yii tẹlẹ, Ajagun-fẹyinti Abdulsalami Abubarkar, ti ni ọrọ ebi to n pa awọn araalu ti n kọja afarada bayii,  o waa rọ ijọba apapọ lati tete wa nnkan ṣe si i kọrọ ọhun too di wahala ti apa ko ni i ka mọ. O ṣalaye pe, ‘‘Ojoojumọ lawọn araalu n kigbe buruku pe ebi n pa awọn, ọrọ ebi naa si ti fẹẹ kọja afarada bayii. Ọpọ araalu ni wọn ko le jẹun lẹẹmẹta lojumọ, agbara kaka lọpọ fi n rọwọ ki bẹnu. Ko sepo bẹntiroolu, owo ọkọ wọn gogo, awọn obi wọn ko le ran awọn ọmọ wọn lọ sileewe mọ nitori ti owo ileewe ti gbowo lori ju bo ṣe yẹ lọ. Ṣe lawọn araalu n jẹ irora fun bi nnkan ko ṣe rọgbọ laarin ilu bayii.

‘’Ohun ta a n bẹ awọn alakooso ijọba orileede yii fun ni pe ki wọn wa wọrọkọ ki wọn fi ṣadaa, ki wọn wa gbogbo ọna lati din ijiya yii ku laarin ilu laipẹ ni. Ki ijọba apapọ, awọn gomina ipinlẹ kọọkan, atawọn alaga ijọba ibilẹ naa ṣapa wọn lati wa ojutuu sọrọ ebi to gbalẹ kan laarin ilu bayii’’.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, lo sọrọ ọhun di mimọ lasiko to n gba awọn ẹgbẹ kan lalejo fun ti ayẹyẹ ọjọọbi rẹ to waye laipẹ yii niluu Minna, nipinlẹ Niger.

ALAROYE gbọ pe awọn ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni ‘Campaign for Democracy and Human Rights, eyi ti Alhaji Abdullah Mohammad, ṣaaju ikọ naa ni wọn lọọ ki Abdulsalami nile rẹ lọjọ Wẹsidee, ọsẹ yii.

Ninu ọrọ to ba awọn ẹgbẹ naa sọ lo ti ke si ijọba apapọ  pe ki wọn tete wa ojutuu sọrọ iyan ati ebi to gbalu kan lasiko yii.

O fi kun ọrọ rẹ pe oun paapaa wa lara igbimọ alabẹṣekele kan to n gba ijọba nimọran nipa bi wọn ṣe le wa ojutuu sọrọ ebi to gbalu kan lasiko yii.

O ni, ‘Gbogbo ẹnu ni ma a fi sọ ọ pe, a ti gba ijọba apapọ lamọran pe fifun awọn araalu lounjẹ iranwọ iyẹn Palliative, ki i ṣe ojutuu sọrọ ebi to wa niluu bayii. Lara ohun ta a gba wọn nimọran lati ṣẹ ni pe ki wọn lọọ ra awọn ounjẹ wa lati ilẹ okeere, ki wọn maa ta a lowo pọọku fawọn araalu, eyi wọn yoo fi le lanfaani lati ra iwọnba ti agbara wọn ba ka. O waa ku sijọba lọwọ lati gbe aba wa yẹwo, ki wọn si mu un lo.

 

 

Leave a Reply