Ọrọ ẹni ti yoo jẹ imaamu ilu Iniṣa ni Ajiboṣo n ba wọn pari to fi ṣubu lulẹ, to si ku- Adetoyi

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọtun ilu Iniṣa, Oloye Adetoyi Abimbọla, to jẹ ọkan pataki lara awọn ọrẹ Oloye Enoch Ajiboṣo, ẹni to jade laye lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde ti ṣapejuwe iku ọkunrin oloṣelu naa gẹgẹ bii alafo nla ti yoo gba ọpọ asiko lati di.

Ọkunrin naa sọ pe kayeefi ni iku Ajiboṣo to jẹ Eesa ilu Iniṣa, nijọba ibilẹ Odo-Otin, nipinlẹ Ọṣun, naa jẹ fun oun.

O ṣalaye pe ọrọ wahala ẹni ti yoo jẹ Imaamu Agba ilu naa ni wọn lọ yanju ni gbọngan nla wọn (Town Hall), niwọn igba to si jẹ pe ẹni ti gbogbo eeyan bọwọ fun ni oloogbe naa, oun naa wa nibẹ lati ran Oluniṣa lọwọ.

O ni gbogbo ariwo ti Oloye Ajiboṣo n pa ninu ipade naa ni pe ki awọn eeyan yẹra fun fifi agbara wa ipo, o si n sọrọ lọwọ lo deede ṣubu lulẹ nibẹ.

Oloye Adetoyi ni kia ni Oluniṣa atawọn ti wọn wa nibẹ ṣeto lati gbe e lọ sileewosan, ṣugbọn bi wọn ṣe gbe e debẹ lawọn dokita kede pe o ti jade laye.

Baba yii fi kun ọrọ rẹ pe ko si aisan kankan to n ṣe Oloye Ajiboṣo, nitori awọn jọ jokoo ṣere laaarọ ọjọ Aiku, Sannde naa, ko too di pe o ku ninu ipade ni nnkan bii aago meji ọsan.

Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni ọfiisi oun ti gbọ si i.

Oloye Ajiboṣo ti figba kan jẹ alaga ijọba ibilẹ Agege, nipinlẹ Eko, ko too di pe o pada lọ siluu rẹ, nipinlẹ Ọṣun.

 

Leave a Reply