Monisọla Saka
Ileeṣẹ Aarẹ orilẹ-ede yii, ti ni irọ to jinna si ootọ ni pe Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ti paṣẹ fun Olori banki apapọ ilẹ wa, Ọlayẹmi Cardoso, lati fipo silẹ nitori owo Naira to n fojoojumọ ja wa silẹ si ti dọla.
Gẹgẹ bi iroyin to n ja ran-in naa ṣe sọ, wọn ni ki Aarẹ too rinrin-ajo lọ si orilẹ-ede China, to ti ṣẹṣẹ de yii lo ti paṣẹ fun Cardoso lati kuro nipo olori CBN, nitori bi ko ṣe ri nnkan kan ṣe si eto ọrọ aje to dẹnu kọlẹ, ati bi owo Naira ṣe n figba gbogbo ja wa silẹ, ti ko niye lori mọ, lo mu ki Aarẹ gbe iru igbesẹ bẹẹ.
Bakan naa ni iroyin ọhun tun sọ pe awọn agbaagba ilẹ Yoruba kan dide nitori ọrọ naa, ti wọn si n bẹ Aarẹ Tinubu lati wo Cardoso ṣe, ko fun un ni anfaani ẹlẹẹkeji lati gbiyanju agbara rẹ, lojuna ati le gbe eto ọrọ aje to n ku lọ naa dide, amọ ti wọn ni ẹyin eti Tinubu ni gbogbo ìpẹ̀ naa n bọ si.
Wọn ni ẹṣẹ kan ṣoṣo ti Cardoso ṣẹ, ti Aarẹ fi n binu si i naa ni pe ko mu gbogbo adehun to ṣe fun Tinubu lasiko to depo, paapaa èyí tó se ninu oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ṣẹ, nigba to ni oun yoo mu agbega ba owo Naira, debii pe laarin ẹẹdẹgbẹrin si ẹẹdẹgbẹrun Naira (700-900), ni yoo jẹ si dọla kan, ti oun yoo si jẹ ki eto ọrọ aje wa rúgọ́gọ́ pada, ko too di ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii.
Diẹ lara iroyin tijọba pe ni ahesọ ọrọ naa ka bayii pe, “Inu Aarẹ ko dun si ọrọ owo Naira si tilẹ okeere, bẹẹ lo n binu pe laarin ọdun kan Cardoso gẹgẹ bi olori banki apapọ, ko le da Naira pada si ẹẹdẹgbẹrin tabi ẹẹdẹgbẹrun Naira si dọla kan, gẹgẹ bo ṣe ti ṣeleri”.
Amọ ninu ọrọ ti Bayọ Ọnanuga ti i ṣe Oludamọran pataki si Aarẹ Tinubu lori iroyin sọ, o ni ko sohun to jọ bẹẹ, ati pe irọ lasan lasan ni ọrọ naa.
“Irọ pata gbaa ni. Aarẹ Tinubu ko ni ki Yẹmi Cardoso fiṣẹ silẹ o”.
Ki a ranti pe owo Naira ile wa ko le duro lẹgbẹẹ dọla, kaka ki o si maa goke si i, paapaa lẹyin ti wọn yan olori banki apapọ tuntun, iyẹn Yẹmi Cardoso, Naira ko tori ẹ gbe pẹẹli, nise lo n walẹ si i.
Ọrọ naa ti waa le debii pe dọla kan ti wọn n ṣẹ si ẹẹdẹgbẹrun ati aadọta Naira (950) lasiko ti Cardoso depo, ti di eyi ti wọn n ṣẹ si ẹgbẹjọ Naira (1,600) bayii.