Ọrọ runrun lẹnu Micheal: Mi o ba ọmọ yẹn sun, mo kan ni ko fọwọ pa ‘’kinni’’ mi ni

Adewale Adeoye

Yunkẹyunkẹ ti baale ile kan, Ọgbẹni Afọlabi Michael, ẹni aadọrin ọdun, mọ ọn ṣe ti ko ba a patapata, adajọ ile-ẹjọ kan ti wọn foju rẹ ba laipẹ yii niluu Eko ko si gba ẹbẹ rẹ wọle, o ti ni ki wọn lọọ ja a sọgba ẹwọn Kirikiri, l’Ekoo, titi di asiko ti igbẹjọ maa fi waye nipa ẹjọ rẹ.

ALAROYE gbọ pe iya ọmọ ọdun mọkanla kan tawọn ọlọpaa forukọ bo laṣiiri nitori ti iwadii ṣi n lọ lọwọ nipa rẹ lo lọọ fẹjọ sun awọn ọlọpaa teṣan Iju, l’Ekoo, pe ninu oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, afurasi ọdaran naa fipa b’ọmọ oun sun. Wọn fọwọ ofin mu afurasi ọdaran naa nile rẹ, ọdọ awọn ọlọpaa to wa lo ti jẹwọ pe loootọ loun fọwọ pa ọmọ naa lara lati le jẹ ki nnkan ọmọkunrin oun ti ko ṣiṣẹ daadaa le gbera soke. O ni ki i ṣe pe oun fipa b’ọmọ naa sun rara gẹgẹ bii ẹsun ti iya rẹ fi kan oun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, sọ pe ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni wọn foju afurasi ọdaran naa bale-ẹjọ fun iwa to lodi sofin to hu pẹlu ọmọ ọdun mọkanla naa.

Alukoro ni ile-ẹjọ ti wọn foju afurasi ọdaran naa ba ko gba ẹbẹ rẹ wọle rara, ẹwọn Kirikiri, niluu Eko, lo sọ pe ki wọn maa gbe e lọ titi di asiko ti igbẹjọ maa fi waye nipa ẹsun ti wọn fi kan an.

Leave a Reply