Faith Adebọla, Eko
Ẹgbẹ ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Afẹnifẹre, ti sọ pe agba to lomi ninu ki i pariwo lawọn fi ọrọ igbesẹ tawọn n gbe lori ọrọ Oloye Sunday Adeyẹmọ tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho ṣe. Wọn lawọn ko sun lori ẹ rara, gbogbo irin to si yẹ kawọn rin lawọn n rin bo tilẹ jẹ pe awọn o ni i sọ awọn irin naa sita lasiko yii, tori gbogbo aṣọ kọ la a sa loorun.
Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre, Oloye Ayọ Adebanjọ, sọrọ yii lasiko to n dahun ibeere latọdọ awọn oniroyin nibi apero agbaye kan ti wọn ṣeto rẹ lati sọrọ nipa erongba ẹgbẹ naa lori ipo ti orileede wa. Ọjọbọ, Tọsidee yii, lapero naa waye n’Ikoyi, l’Ekoo.
Baba Adebanjọ ni oriṣiiriṣii igbesẹ ni ẹgbẹ Afẹnifẹre n gbe lati ri i pe wọn tu Sunday Igboho silẹ, o ni bawọn ṣe n ṣiṣẹ lori iṣẹlẹ naa pẹlu awọn alaṣẹ tọrọ kan, bẹẹ lawọn n ṣiṣẹ pẹlu awọn alaṣẹ orileede Olominira Benin.
“Ọrọ to gbẹgẹ lọrọ yẹn, ẹ si le reti ki n maa sọ gbogbo igbesẹ ti a ti gbe ateyi ti a n gbe lọwọlọwọ ni gbagba ita bayii. Iṣẹ n lọ lori ẹ, a fọwọ lẹran, a o si ni i duro titi ta a fi maa ṣaṣeyọri. Adura ni kẹ ẹ maa fi ran wa lọwọ.”
Bakan naa ni baba ẹni ọdun mẹtalelaaadọrun naa bẹnu atẹ lu iwa ojo to wọpọ laarin ẹya Yoruba. O ni ominira tawọn eeyan n gbadun lasiko yii, awọn kan ni wọn ti ja fun un, ti wọn si fi ẹmi wọn lelẹ lori ẹ, bo tilẹ jẹ pe a o ti i de ibi ti a fẹ, o si ṣe pataki kawa naa pinnu lati ja titi ta a fi maa de ibi to yẹ.
“Wọn o ki i fi ominira bẹẹyan, niṣe leeyan n ja fun un. Iwọnba ominira tawọn eeyan n gbadun lasiko yii, awọn kan ni wọn ti ja fun un, ọpọ lo dero ẹwọn tori ẹ, awọn mi-in padanu ẹmi wọn kawa le gbadun.
Ṣugbọn ọpọ eeyan lo ti di ojo lonii, ko sẹni to fẹẹ ja tabi ku. Ẹgbẹ Afẹnifẹre ki i ṣe ti idaluru tabi iditẹ sijọba o, ṣugbọn gbogbo ohun to ba maa fun ọmọ Yoruba lanfaani lati wa ni ipo to yẹ ẹ lawujọ lawa duro fun, a o si ni i yẹsẹ lori ẹ.