Ọrọ ti Faṣoranti sọ gba omi loju mi-Ayọ Adebanjọ

Faith Adebọla

Olori ẹgbẹ Afenifẹre, Baba Ayọ Adebanjọ ti fi ẹdun ọkan rẹ han lori wahala to n lọ ninu ẹgbẹ naa ati bi awọn kan ṣe fẹẹ lo baba agbalagba toun naa jẹ agba ẹgbẹ yii, Baba Faṣoranti lati da ẹgbẹ naa ru.

Adebanjọ sọrọ yii ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu ALAROYE, nibi to ti ṣalaye pe Faṣoranti funra rẹ lo pe oun ni nnkan bii meji sẹyin pe ki oun waa gba ipo adari ẹgbẹ naa. O ni baba yii ni oun ti da gba, ko si si agbara mọ lati tẹsiwaju. Beẹ lo sọrọ didun lati fi po oun le pe oun nikan loun le ṣe e, lẹta to si kọ nigba naa wa kaakiri.

O ni oun ko kọkọ fẹẹ gba ipo naa, ṣugbọn oun ko feẹ fi sipo naa silẹ fun awọn to le ba a jẹ lo jẹ ki oun gba lati ṣe e.

Adebanjọ ni, ọrọ ti Faṣoranti sọ pe oun ni alaga ẹgbẹ Afẹnifẹre gba omi loju oun, o si ko ibanujẹ ọkan ba oun, nitori awọn kan ni wọn n ti baab naa lati da ẹgbẹ afẹnifẹre ru.

Adebanjọ ni, ‘‘Igba to rẹ Faṣoranti lo kọwe, to ni oun ko ṣe olori ẹgbẹ Afẹnifẹre mọ. Bii igba to rẹ Baba Adesanya nigba naa lọhun-un ni, ti baba naa ni awọn ko ṣe olori ẹgbẹ Afẹnifẹre mọ. Oun lo ni Ayọ Adebanjọ, maa bọ, iwe yẹn wa ti wọn n gbe kaakiri. O pọn mi sibẹ, to ni emi nikan ni mo le ṣe adari Afẹnifẹre, o ni o ti rẹ oun, agba ti de, ni bii ọdun meji sẹyin.

‘‘Igba to si gbe e wa nigba yẹn, mi o fẹẹ gba a nitori awọn ọrọ kan to ti ṣẹlẹ, mo waa wo o pe ti mo ba ni mi o gba a, ki lo maa ṣẹlẹ si Afẹnifẹre, awọn wo lo fẹẹ ṣe e, ṣẹ awọn ko gbona ko tutu yẹn ni.

‘‘Mi o fẹẹ sọrọ nipa awọn ti wọn tẹle Tinubu lọ si Akurẹ, nitori mi o fẹ ki nnkan ti wọn fẹ ko ṣẹlẹ ṣẹlẹ. Ti mo ba bẹrẹ si i mu wọn lọkọọkan, iyẹn la maa maa sọ. Latọsẹ to lọ, ọrọ Afẹnifẹre ni wọn n sọ, wọn ko ṣe maa sọrọ eto idibo, Tinubu naa lo ko wa fun awọn Hausa, gbogbo nnkan ti a ti jọ gba pe wọn maa ṣe nigba ti wọn ba dori ijọba bii gomina nigba yẹn ni ko le sọ mọ bayii nitori pe Buhari n tan an pe oun maa fi i ṣe aarẹ.

‘‘Gbogbo awọn tẹ ẹ n sọ yii ko pa mi lẹkun o, ti Baba Faṣoranti lo pa mi lẹkun, wọn pa mi lẹkun naa ki i ṣe kekeere, nitori ti mo ba ro bi a ṣe yan an ati idi ta a fi yan an, pe oun ni yoo waa fi ọrọ alaga fọ ẹgbẹ Afẹnifẹre, ko daa o, ko si si si ẹni to ṣee fun ilẹ Yoruba to jẹ ẹ gun.

‘‘Nigba ti mo gbọ pe o sọ pe oun ni alaga Afẹnifẹre, haa, ẹkun gbọn mi. Ki lemi fẹẹ fi ọrọ Afẹnifẹre ṣe ni aye mi. Nibi ti mo de nidii oṣelu niluu yii, ko si nnkan ti mo fẹẹ jẹ ninu ẹgbẹ Afẹnifẹre ti mi o ti i jẹ. Bi mo kuro nibẹ, bi mo wa nibẹ, ko si nnkan ti mi o ti i jẹ. Itan Naijiria yii ko pe, ki wọn too sọ itan Naijiria ki Ayọ Adebanjọ ma wa nibẹ, ko ti i pe, nitori mo ti ṣe gbogbo iyẹn kọja.

‘‘Ko ma bajẹ, paapaa awọn ti wọn fẹẹ yii nnkan pada ni mo ṣe duro ni, emi, ni ẹni ọdun mẹrinlelaaadọrun-un. Kin ni mo fẹẹ da ti Ọlọrun ko ti ṣe fun mi, mi o lọmọ ti mo fẹẹ sanwo ẹ nileewe, mi o ni ojukokoro pe ile ti mo wa yii ko tẹ mi lọrun. Mi o ni mo fẹẹ lọ si Jamaica tabi ki n maa kiri ilu kiri, mo wa ninu ile yii, mo mọ pe ko jo, ki waa ni mo n wa.

‘‘iyẹn la dẹ ro pe Baba Faṣoranti, gbogbo ẹ naa ni Ọlọrun ti ṣẹ fun un,. Ki lo n wa nigbẹyin aye rẹ ti ko ri to fi n tele awọn ọmọ  ti wọn fẹẹ da nnkan ru yii’’.

Bẹẹ ni Baba Adebanjọ sọ ninu ifọrọwerọ naa.

Leave a Reply