Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Latari bi ọrọ arun Koronafairọọsi ṣe n fẹju bii ina ẹẹrun kaakiri orileede yii bayii, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe ileewosan aladaani ti aṣiri ba tu pe wọn ti n tọju arun yii yoo fimu kata ofin.
Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ Ọṣun, Funkẹ Ẹgbẹmọde, fi sita laipẹ yii lo ti ni o jẹ ibanujẹ ọkan funjọba pe awọn araalu ko naani arun naa mọ.
O ni pẹlu bijọba ṣe n ke lojoojumọ pe eleyii to wa lode bayii ti wọn pe ni Delta Variance lagbara ju eyi to wa tẹlẹ lọ, to si yara pa ẹni to ba ti mu, sibẹ, ọwọ yẹpẹrẹ ni ọpọlọpọ fi n mu un.
Ẹgbẹmọde fi kun un pe ijọba yoo gbe igbesẹ to lagbara lori awọn to ni ileewosan aladaani ti wọn n tọju alarun Korona, eleyii to lodi si ofin.
O kilọ fun gbogbo awọn dokita ti wọn n ṣan aṣọ iru rẹ ṣoro lati jawọ, ki wọn si mọ pe ayẹwo arun Korona ti wa lara awọn ayẹwo ti wọn gbọdọ kọkọ maa ṣe fun ẹnikẹni to ba wa sọdọ wọn fun itọju.
O ni ti awọn dokita yii ba ti kẹẹfin awọn ami arun yii lara ẹni to ba waa gbatọju lọdọ wọn, ki wọn tete dari wọn si awọn ibudo itọju arun naa tijọba ti gbe kalẹ.
Ẹgbẹmọde waa ke si gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun lati tẹra mọ awọn ilana ti ko ni i jẹ ki wọn lugbadi arun naa ati eyi to n dena itankalẹ rẹ.