Ibrahim Alagunmu
L’Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un yii, ni ile-ẹjọ giga kan to filu Ilọrin ṣebujokoo ti ni ki wọn lọọ fi oṣiṣẹ to wa fun akoso ni lẹburu kekere (Administrative Officer) ni ileewosan olukọni Fasiti Ilọrin (UITH), Mokuolu Oluwakayọde Samuel, ẹni ọdun marundundinlaaadọta (45), sahaamọ ọgba ẹwọn titi ti igbẹjọ yoo fi waye lori ẹsun jibiti obitibiti miliọnu ti wọn fi kan an.
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọku-mọku nilẹ yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ẹka tilu Ilọrin, lo wọ afurasi naa lọ si kootu lori ẹsun jibiti ti wọn fi kan an.
Aliyu Adebayọ to ṣoju EFCC nile-ẹjọ sọ fun adajọ pe ẹsun akọkọ ti wọn fi kan afurasi ni pe laaarin oṣu Kin-in-ni, si osu Kọkanla, ọdun 2020, ni Mokuolu sọ dukia Arabinrin Bukọla Ọladẹhinde Ọmọdona, towo rẹ le ní miliọnu mẹrin (N4, 520,531), di tara rẹ, leyii to ba adehun to wa laarin oun ati arabinrin naa jẹ.
Ẹsun keji ti wọn tun fi kan an ni pe laaarin oṣu Kọkanla, ọdun 2020, si osu Kin-in-ni, ọdun 2021, afurasi yii tun lu Arabinrin Ọbanla Dorcas Bukọla ni jibiti miliọnu mẹta ati ẹgbẹrun lọna oodunrun Naira (N3, 300.00). Agbefọba, Aliyu Adebayọ, sọ fun ile-ẹjọ pe onijibiti paraku ni afurasi naa, ki adajọ tete taari ẹ si ọgba ẹwọn, ko lọọ máa gbatẹgun níbẹ titi ti iwadii yoo fi pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.
Nigba to n fesi sawọn ẹsun ti agbefọba fi kan an, Mokuolu ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.
Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Mahmoud Abdulgafar, paṣẹ ki wọn taari afurasi ọdaran naa sogba ẹwọn, o sun igbẹjọ si ọgbọnjọ, oṣu Karun-un, ọdun yii.