Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ajọ eleto idibo lorileede yii, Independent Electoral Commission (INEC), ti sọ pe awọn ẹgbẹ oṣelu mẹta ti wọn ko kunju oṣuwọn ajọ naa nipinlẹ Ọṣun ko ni i lanfaani lati kopa ninu idibo gomina ti yoo waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii.
Ninu atẹjade kan ti alaga igbimọ ajọ naa to n ri si eto iroyin ati iforukọsilẹ awọn oludibo, Festus Okoye, fi sita lo ti sọ eleyii di mimọ.
Awọn ẹgbẹ oṣelu naa ni Action Alliance (AA), African Democratic Congress (ADC) ati All Progressives Grand Alliance (APGA).
Okoye ṣalaye pe alaga apapọ ẹgbẹ AA ati akọwe rẹ ko fọwọ si fọọmu erongba lati fihan pe ẹgbẹ wọn fẹẹ dije ninu idibo naa.
Ni ti ẹgbẹ ADC ati APGA, o ni ọjọ-ori awọn ti wọn fi silẹ fun ajọ INEC gẹgẹ bii igbakeji-gomina wọn kere si eyi to wa ninu alakalẹ ajọ naa.
O ni awọn ti kọwe si awọn ẹgbẹ oṣelu mẹtẹẹta ti ọrọ kan, eyi si tumọ si pe ẹgbẹ oṣelu mẹẹẹdọgbọn ni yoo kopa ninu eto idibo naa.