Aderohunmu Kazeem
Ẹgbẹ ẹya Ibo kan ti wọn n pe ni Ohaneze ti sọ pe ẹnikẹni tabi ẹya kan ni Naijiria yii, to ba foju abuku wo iwọde tawọn ọdọ ṣe ta ko SARS, ọta ilọsiwaju Naijiria ni iru ẹni bẹẹ.
Akọwe ẹgbẹ Ohaneze-Ndigbo, Ọmọọba Uche Achi-Okpaga, sọ pe gbogbo awọn ti wọn n gbiyanju lati sọ pe iwọde tawọn ọdọ ṣe ta ko awọn SARS, wọn fẹẹ fi da nnkan ru fun Buhari ni, ni yoo kuna patapata.
O ni iwọde tawọn ọdọ ṣe kaakiri orilẹ-ede yii ti fi han pe ayipada nla ti bẹrẹ si i ṣẹlẹ ni Naijiria bayii, ati pe ẹya kan abi awọn eeyan kan ti wọn ba ṣi n wo o pe bi a ṣe n ba a bọ tẹlẹ lohun gbogbo yoo maa lọ, niṣe niru wọn n tan ara wọn jẹ.
Ọkunrin yii ni wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ ni o, wọn ko ti i ri nnkan kan, ati pe ọrọ iwọde ta ko SARS yii, bii ẹni ṣẹṣẹ n mu ẹyẹ bọ lapo ni. O fi kun un pe kariaye ni ọrọ ẹrọ ayelujara ti tan de bayii, ti ẹya kan ba wa n sọ pe oun ko ni i lo o, tabi ṣamulo ẹ, niṣe ni omi ilọsiwaju maa gbe iru wọn lọ.
Awọn ipinlẹ ti wọn pe ara wọn ni Aarin-Gbungbun, iyẹn Middle Belt, ni tiwọn sọ pe ọrọ ti awọn Gomina ilẹ Hausa yii atawọn ọba alaye wọn sọ ko ba laakaye kankan mu, ati pe ero tiwọn ni wọn sọ yẹn.
Dokita Bitrus Porgu, ẹni ti i ṣe olori awọn eeyan agbegbe yii sọ ninu ifọrọwerọ kan pe ipade ti awọn gomina atawọn ọba alaye ọhun lọọ ṣe ni Kaduna fihan pe awọn to lọ si ipade naa ati Aarẹ Muhammed Buhari jọ n da Naijiria ru ni. O ni ṣe wọn fẹẹ sọ pe awọn nifẹẹ si bi orilẹ-ede yii ṣe ri, ti nnkan n daru si i lojoojumọ ni.
Bẹẹ lo ke si awọn ti wọn ṣepade ọhun lati tun inu wọn ro daadaa, nitori nnkan ko lọ deede ni Naijiria lasiko yii, bẹẹ lohun ti wọn sọ, ero inu wọn ni, ki i ṣe ti gbogbo ọmọ Naijiria, abi awọn eeyan agbegbe tawọn.
Ni ti Afẹnifẹre, akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Yinka Odumakin, sọ pe nibi ta a ba de yii, niṣe lo yẹ ki anfaani wa fun awọn eeyan, boya ki Naijiria ṣi wa lọkan ṣoṣo tabi ki kaluku di agbegbe ẹ mu, ti a ba fẹẹ ni orile-ede to duro daadaa.
O ni, “Ohun ti ko ye wọn ni pe ariwo titako SARS tawọn ọdọ n pa kiri nigba yẹn, ki i ṣe pe wọn fẹẹ fi doju ijọba kankan bolẹ, bi ko ṣe lati fi wa ojuutu si bi ọjọ ọla Naijiria yoo ṣe dara ni.
Odumakin ni ti a ba waa ri awọn kan ti wọn n gbe e kiri pe wọn fẹẹ fi wo ijọba Buhari lulẹ ni, a jẹ pe ohun kan soso to wa lọkan tiwọn ko ju bi wọn yoo ṣe maa dari orilẹ-ede yii lọ.