Faith Adebọla, Eko
Bo ba jẹ pe ọkunrin ti wọn porukọ ẹ ni Kalu Nnanna ṣoogun afẹẹri ati aṣegbe ni, a jẹ pe babalawo ẹ ti lu u ni jibiti gidi, tori lẹyin to ti lọọ jale lọsibitu kan, to si ti sa lọ pẹlu ero pe ẹnikẹni ko ri oun laṣiiri ẹ tu, tọwọ si ba a, wọn ti ṣedajọ ẹwọn oṣu mẹẹẹdogun fun un nile-ẹjọ.
Nigba tawọn ọlọpaa ikọ ayarabiaṣa (Rapid Response Squard) wọ afurasi ọdaran naa dele-ẹjọ alagbeeka kan laaarọ ọjọ Aje, Mọnde yii, wọn ṣalaye pe ẹrọ kọmputa alaagbeletan (laptop) kan to jẹ ti ọkan lara awọn oṣiṣẹ ileewosan Jẹnẹra Gbagada lo ji, wọn lẹni to ni kọmputa ọhun dide lọọ jẹ ounjẹ ọsan ni, ko too de ni kọmputa to fi sori tabili rẹ ti dawati, ọsẹ to kọja ni wọn lo huwa buruku ọhun.
Ṣugbọn Kalu ko mọ pe kamẹra aṣofofo ti wa kaakiri ọfiisi ọsibitu naa, kamẹra yii lo taṣiiri ole to ji kọmputa lọ, ni wọn fi lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Gbagada, wọn si fi fọto ati fidio to ṣafihan bi ole yii ṣe yọ kẹlẹ wọle lọọ ji kọmputa han.
Nigba t’Ọlọrun maa mu Kalu, aṣọ to wọ sọrun lọjọ to lọọ jale yii naa lo wọn lọjọ Aiku, Sannde yii, bawọn ọlọpaa patiroolu RRS si ṣe foju kan an lẹgbẹẹ titi ni wọn ranti fidio afurasi ọdaran ti wọn n wa, ni wọn ba gan an lapa, wọn si fi pampẹ ofin gbe e.
Kalu ko wulẹ jampata, o jẹwọ pe loootọ loun huwa ọdaran naa, bẹẹ naa lo si jẹwọ ni kootu pe ebi lo n pa oun toun fi lọọ jale, o si da kọmputa naa pada. Wọn tun lo jẹwọ pe oun o ṣẹṣẹ maa jale, ṣugbọn ọsibitu loun ti maa n jale toun, awọn nnkan bii foonu, goolu ati dukia bẹẹ loun maa n ji lawọn ileewosan kaakiri agbegbe Surulere, Ikeja ati Yaba.
Ṣa, Adajọ ti paṣẹ pe ko lọọ fẹwọn ọdun kan ati oṣu mẹta jura.