Ọwọ aṣọbode tẹ dẹrẹba oniṣowo to n ta ayederu oogun nipinlẹ Ọyọ

Ọlawale Ajao, Ibadan
Awakọ gbajumọ oniṣowo oogun kan nigboro Ibadan, ti dero ahamọ awọn ọlọpaa bayii. Awọn aṣọbode ni wọn mu un pẹlu ọpọlọpọ oogun to gbe lati ilẹ okeere wọ orileede yii wa, ṣugbọn ko si ojulowo kan ninu awọn oogun naa, ayederu pọnbele ni gbogbo wọn.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lolu ileeṣẹ wọn to wa l’Agodi, n’Ibadan, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọgbọnjọ (30), oṣu Kẹwaa, ọdun 2024 yii, ọga agba ileeṣẹ aṣọbode ẹkun ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun, Nigeria Customs Service (NCS), Ọmọwe Ben Oramalugo, fidi ẹ mulẹ pe niluu Ìwéré-Ilé, nipinlẹ Ọyọ, lawọn ti mu awakọ to ba gbajumọ onifayawọ oogun naa ko awọn ayederu oogun ọhun wọle lati orileede mi-in.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “A ti fa afurasi ọdaran ọhun le awọn ọlọpaa lọwọ. Bẹẹ la ti gba gbogbo ayederu oogun ọhun lọwọ ẹ, a si ti ranṣẹ pe ọga ajọ to n ri si oogun ati ohun jijẹ lati waa gbe awọn oogun yii. Lonii naa la o si fa gbogbo ẹ le wọn lọwọ ni kete ta a ba ti pari ipade oniroyin yii.”

Nigba to n jíyìn iṣẹ ìríjú wọn laarin oṣu Kẹsan-an ati oṣu Kẹwaa, ọdun yii, Ọmọwe Ọramalugo sọ pe owo to ku diẹ ko pe biliọnu mẹrinlelogun Naira (N 24bn) lawọn aṣọbode ẹkun yii pa wọle sapo ijọba apapọ laarin oṣu meji yii. Bẹẹ ni wọn ri obitibiti ẹru gba lọwọ awọn onifayawọ ti wọn n ko ọja ilẹ okeere wọ orileede yii lọna ti ko bofin mu.

O ṣalaye pe, “Awa ileeṣẹ aṣọbode ẹkun ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun, n ṣe ilanilọyẹ fawọn araalu lati jẹ ki wọn mọ ewu to wa ninu ka maa ko ọja wọle lati ilẹ okeere lọna aibofinmu.

Bakan naa la n ṣiṣẹ ni ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ileeṣẹ alaabo yooku. Gbogbo iwọnyi si n seeso rere, nitori awọn igbesẹ yii ti mu adinku ba bi awọn eeyan ṣe n ko nnkan wọ orileede yii lọna aitọ.

“Eeyan le ṣaisan ko maa loogun laimọ pe nnkan ti yoo ṣeku pa oun loun n lo. Idi ni pe ayederu oogun pọ nigboro. Ọpọ ninu awọn ayederu oogun wọnyi lo si jẹ pe lati ilẹ okeere ni wọn ti n ko wọn wa. Ohun ta a fẹẹ ṣe bayii ni lati ni akanṣe ajọṣepọ pẹlu ajọ to n gbogun ti oogun oloro.

“Naijiria lo n pese irẹsi ju lọ nilẹ Afrika, sibẹsibẹ, awọn oniṣowo n ṣe fayawọ irẹsi wa sorile-ede yii, iru aṣa bẹẹ si maa n ṣakoba fun nnkan ti eeyan ba n pese labẹle ni.”

Lara awọn ẹru ti wọn gba lọwọ awọn kọ̀lọ̀rànsí eeyan naa ni ojilenirinwo o din meje (433) apo irẹsi, apo nla nla mọkanlelọgọta (61) to kun fun aloku aṣọ pẹlu aloku taya ọkọ mẹtalelaaadọrun-un (93).

Eyi to buru ju ninu awọn ẹru ti wọn gba lọwọ awọn fayawọ oniṣowo wọnyi ni oogun oloro ti wọn n pe ni igbo, kinni buruku ọhun to kun inu apo nla nla mọkandinlaaadọta (49) bamubamu ni wọn gba lọwọ awọn arufin eeyan naa pẹlu ọpọlọpọ ayederu oogun Oyinbo.

Lara awọn ayederu oogun ọhun ni: paali mẹrindinlaaadọta (47) to kun fun omi abẹrẹ ti wọn n pe ni Analgin, apo nla nla mejidinlaaadọrin (68) to kun fun oogun kokoro ti wọn n pe ni Amoxillin oni káńsù, apo mọkanla to kun fun Ampiclox, oogun onikoro ti wọn n pe ni Chloramphenicol, eyi to kun inu apo nla nla marun-un bamubamu, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Gbogbo oogun ọhun lọga awọn kọ́sítọ́ọ̀mù yii ti fa le ajọ NAFDAC lọwọ. Abilekọ Roseline Ajayi, to jẹ oludari ẹka to n gbogun ti oogun oloro ninu ajọ NAFDAC lo gba gbogbo oogun ọhun lorukọ wọn.

Obinrin naa si ti ṣeleri pe niṣe lawọn yoo ba gbogbo oogun naa jẹ patapata. Idi ni pe ọpọ ninu wọn lo lewu fun agọ ara ọmọniyan, nitori ayederu ni gbogbo wọn.

Bakan naa lọmọ ṣori lọdọ awọn NDLEA, iyẹn  ajọ to n gbogun ti lilo ati gbigbe egboogi oloro, nitori ẹni to ṣoju ọga agba ajọ naa, CSC Abogunrin Ọlatunde, sọ pe niṣe lawọn paapaa yoo dana sun gbogbo oogun oloro ọhun patapata.

Leave a Reply