Faith Adebọla, Eko
Meje lara awọn ọmọ ganfe to n digunjale loju popo lagbegbe Ikẹja ati lọna marosẹ Mile 2, ti bọ sakolo awọn agbofinro, awọn ikọ ayara-bii-aṣa RRS (Rapid Response Squard) lo mu wọn lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keji yii.
Ayika ileetaja igbalode Shoprite, to wa nitosi Alausa, n’Ikẹja, ni wọn ti mu mẹta lara awọn meje naa torukọ wọn n jẹ; Kọlawọle Anifowoṣe, ẹni ogun ọdun, Patrick Ameke, ẹni ọdun mọkanlelogun ati John Brito, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn. Wọn ni niṣe ni wọn n ja baagi gba lọwọ awọn ero atawọn kọsitọma to lọọ raja nileetaja ọhun.
CSP Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi to n dari ikọ RRS l’Ekoo sọ ninu atẹjade to fi soju opo ayelujara RRS pe awọn alaṣẹ ileetaja Ikẹja City Mall, nibi ti Shoprite wa, lo kọwe sawọn pe awọn adigunjale atawọn janduku ọmọ iṣọta ko jẹ kawọn onibaara awọn rimu mi lagbegbe naa, bi wọn ṣe n lọ wọn lọwọ gba, ti wọn n ja foonu ati baagi wọn gba, bẹẹ ni wọn n da wahala silẹ.
Eyi lo mu ki wọn da awọn ọlọpaa ti ko wọṣọ sagbegbe naa, ti wọn si bẹrẹ si i ṣọ awọn kọlọransi ẹda yii, tọwọ fi ba mẹta ninu wọn.
Ni ti awọn mẹrin tọwọ tẹ lagbegbe Mile 2, Ẹgbẹyẹmi ni ọpẹlọpẹ awọn oṣiṣẹ ẹgbẹ onimọto NURTW, awọn ni wọn jẹ kawọn ọlọpaa ri awọn afurasi mẹrin naa mu lasiko ti wọn n da awọn onimọto lọna l’Ọjọbọ, Tọsidee, yii kan naa.
Orukọ awọn mẹrin tọwọ ba ni Mile 2 ni Ṣẹgun Peters ati Nurudeen Suraj, ẹni ọdun mejilelogun ni wọn, Dennis Ikuvbogie, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ati Kabiru Odeh, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn.
Ẹgbẹyẹmi tun ṣalaye pe meji ninu awọn afurasi ọdaran naa, Nurudeen Suraj ati Anifowoṣe Kọlawọle ti ko sakolo ọlọpaa ri, ti wọn si sọ wọn sahaamọ fun ẹsun afọwọra. Teṣan Agboju ni wọn fi wọn si nigba naa ki wọn too rẹni gba beeli wọn. O lawọn ti kilọ fun wọn lati jawọ ninu iṣẹẹbi, wọn si ṣeleri pe awọn o ni i ṣe bẹẹ mọ, ṣugbọn ọwọ palaba wọn tun ṣegi.
Wọn ni bii ẹni to n tọrọ baara lawọn mi-in lara awọn maa n ṣe, awọn kan si maa n ko ibomu ti wọn yoo dibon bii ẹni pe wọn n ta a dani, kawọn eeyan ma baa tete fura si wọn titi ti wọn aa fi raaye ṣe wọn ni ṣuta.
O ni iwadii ti n lọ lọwọ gẹgẹ bi aṣẹ ti Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Abiọdun Alabi, pa, awọn ọtẹlẹmuyẹ si ti n wa awọn adigunjale ẹlẹgbẹ wọn to sa lọ. Ti iwadii ba ti pari ni wọn maa taari wọn siwaju adajọ ki wọn le fimu kata ofin.