Ọwọ EFCC tẹ ọmọ Yahoo mẹjọ, eyi lawọn nnkan ti wọn ba lọwọ wọn

Adewale Adeoye
Mẹjọ lara awọn ọmọ Yahoo kan ti wọn n ṣe gbaju-ẹ lori ẹrọ ayelujara lọwọ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku (EFCC), ẹka tilu Abuja, ti tẹ l’Ọjọbọ, Tosidee, ọjọ kọkanla, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, ti wọn si ti n ran ajọ naa lọwọ ninu iwadii wọn, kọwọ le tẹ awọn yooku wọn gbogbo. Lẹyìn tó wọn ba mu awọn to ku ni wọn yoo ko gbogbo wọn lọ sile-ẹjọ.
Awọn tọwọ tẹ ni: Usifo Mophy, Eze Richard, Abdulkadir Sadiq, Emmanuel Joseph, Tuoyo Kelvin, Joel Omojeve Joshua Omojeve ati Oreva Omojeve.
Alukoro ajọ naa, Wilson Uwujaren, ni awọn owuyẹ kan ni wọn waa fọrọ awọn ọmọ Yahoo naa to awọn leti nipa ibi ti wọn n gbe kaakiri lagbegbe ọhun, tawọn si tara ṣaṣa lọ sibẹ lati fọwọ ofin mu gbogbo wọn. Lara ibi ti ọwọ ti tẹ wọn ni ‘EFAB Estate’, Gwarimpa, Federal Housing Authority Estate, Nyanya ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lara awọn ẹru ofin ti wọn ba lọwọ wọn ni: Foonu igbalode mẹwaa, ẹrọ kọmputa alaagbeletan HP, MọtoToyota Camry meji, mọto Mercedes Benz C300 kan ati mọto Lexus RX 350 kan.
O ni gbara tawọn ba ti pari iwadii awọn tan lawọn ọdaran naa yoo foju bale-ẹjọ

Leave a Reply