Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọwọ fijilante ti tẹ awọn ajinigbe marun-un ti wọn n yọ wọn lẹnu nijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ Kwara.
Ni nnkan bii aago mẹwaa owurọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọṣẹ yii, lọwọ tẹ awọn ajinigbe ọhun ni buba wọn ninu igbo kan ti wọn maa gbe awọn ti wọn ba ji gbe pamọ si lati ṣiṣẹ buruku wọn. Oniruuru ohun ija oloro ni wọn ba lara wọn bi awọn ibọn loriṣiiriṣii ọbẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Olori awọn fijilante ẹkun Aarin Gbungbun Ariwa Naijiria, Alaaji Ibrahim, to ba ALAROYE sọrọ fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni lati Ilọrin, ti i ṣe olu ipinlẹ Kwara, lawọn ti gbọ iroyin pe awọn ajinigbe naa n bẹ ninu igbo kan nijọba ibilẹ Ekiti, nipinlẹ Kwara, lawọn fi ran awọn fijilante lọpọ yanturu lọ sibẹ. Nibẹ ni wọn ti ri marun-un ninu awọn ajinigbe ọhun mu pẹlu ohun ija oloro lọwọ wọn.