Adewale Adeoye
Ṣe lọrọ di bo o lọ yago fun mi laaarọ kutukutu l’Ọjọru, Wesidee, ọjọ kejila, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii, lagbegbe Akute ati Alagboole, nijọba ibilẹ Ifọ, nipinlẹ Ogun.
Awọn ọlọkada agbegbe naa lo kọju ija sawọn agbero to n gbowo orita lọwọ wọn nigba gbogbo. Ohun to ṣokunfa ija ọhun ko ju bi awọn agbero naa ṣe ṣafikun owo orita tawọn ọlọkada naa n san fun wọn lojoojumọ tẹlẹ lọ.
Ẹnikan tọrọ naa ṣoju ẹ ṣalaye pe, ‘‘Kẹ ẹ si maa wo o, ẹẹdẹgbẹrin Naira (N700) lawọn ọlọkada naa n san fawọn agbero ọhun tẹlẹ lojumọ, ojiji ni wọn sọ owo orita ọhun di ẹgbẹrun kan ati irinwo Naira (N1400) mọ awọn ọlọkada ọhun lọwọ. Ko sẹni ti ko mọ pe ilu le lakooko yii, nibo gan-an lawọn agbero ọhun ti fẹ kawọn ọlọkada yii ri owo naa fun wọn pẹlu pe epo bẹntiroolu ti gbowo lori bayii, ki wọn too ra epo, ki wọn too sanwo orita fawọn agbero wọnyi, ki awọn naa too ri owo mu lọ sile lati fi bọ iyawo ati ọmọ, ki i ṣe nnkan to rọrun rara’.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ni ẹmi ẹni kan ba iṣẹlẹ naa lọ, ko si apẹẹrẹ bẹẹ nigba tawọn oniroyin debi iṣẹlẹ naa rara, ṣugbọn ohun to foju han kedere ni pe awọn kan ti da omi alaafia ilu naa ru gidi, tawọn eeyan si n sa kijo-kijo kaakiri ilu naa nitori pe wọn ko mọ itu tawọn agbero ọhun tun le fi awọn ọlọkada ọhun pa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, S.P Ọmọlọla Odutọla, to fidii iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe awọn ti gbọ nipa ija igboro kan to bẹ sile niluu naa, ti wọn si ba dukia olowo iyebiye jẹ lakooko ija ọhun.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni i foju to daa wo awọn ọlọkada tabi awọn agbero ti wọn ba fẹẹ da ilu ru nipinlẹ naa bayii.