Owo mareeji ni mo n wa ti mo fi bẹrẹ si i digun jale-Mohammed

Faith Adebọla

  Ẹni ti o gbọ tẹnu ẹga ni yoo sọ pe ẹyẹ oko n paato ni, ṣugbọn  ọpọ eeyan lo n sọ pe ọrọ rirun lọmọkunrin ẹni ogun ọdun kan,  Nura Mohammed, n sọ jade lẹnu ni teṣan ọlọpaa nigba tọwọ ba a nibi to ti n ji ọkada ẹni ẹlẹni kan gbe, o ni ki wọn ṣaanu oun, ki i ṣe pe ole wu oun lati ja bẹẹ naa, oun ti dajọ iyawo sọna, afẹsọna oun si fẹ kawọn ṣe mareeji alarinrin, igba toun si ṣiṣẹ titi towo kọ ti o jọ soun lapo, to jẹ apana lowo n ba lọ, loun ba ni koun gbiyanju ọkada jijigbe yii wo, ko si ti i pẹ toun at’ọrẹ oun bẹrẹ ole ọhun ti wọn fi mu awọn yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa, SP Sulaiman Nguroje, lo fiṣẹlẹ yii lede l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila yii, nigba tọwọ tẹ Nura, ọmọ bibi ilu Mọdire, nijọba ibilẹ Girei, ati ẹni keji ti wọn jọ n jale, Muhammed Bello, ẹni ọdun mẹrinlelogun, ọmọ bibi adugbo Jili Unguwan Wakili, to wa nijọba ibilẹ Fufore, nipinlẹ Adamawa.

Nura fẹnu ara ẹ ṣalaye pe iṣẹ ọkada loun n ṣe, oun n fi ọkada gbero lagbegbe naa ni.

O ni koun sootọ, oun loun ro o lọkan, toun si fọrọ naa lọ Muhammed pe ko jẹ kawọn maa jale, tori oun ro pe ọna to ya toun fi le tete ri owo toun n wa niyẹn. O loun fẹẹ ṣe igbeyawo, oun si ti ni afẹsọna tawọn jọ n wo ọjọ mareeji lọọọkan, kọrọ oun maa waa lọọ di ala taja ba la, inu aja lo n gbe, loun fi pinnu pe idi jiji ọkada gbe loun yoo ti ri owo toun nilo.

Muhammed naa ṣalaye pe bọrọ ṣe jẹ lekeji oun sọ yẹn, o ni loootọ lo fi ipinnu ẹ lati jale ko le rowo wẹdin (wedding) tu jọ lọ oun, oun si gba lati kun un lọwọ.

O laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlogun, oṣu Disẹmba yii, ni Nura tun ran oun leti lori aago, awọn si fi ipade si ọjọ Mọnde to tẹle e. Laaarọ ọjọ Mọnde, ọjọ kọkandinlogun ọhun, awọn ni ki ọlọkada kan gbe awọn lọ si adugbo Parda, nijọba ibilẹ Furore, amọ nigba tawọn n lọ lọna, oun mọ-ọn-mọ ju fila oun sori odo kan tawọn fẹẹ gba ẹgbẹ ẹ kọja, ṣugbọn oun ṣe bii pe o ṣeeṣi ja bọ ni, ki ọlọkada naa le duro, tori awọn ti ri i pe ọkada rẹ tuntun, oju awọn si wọ ọ, awọn si fẹ ẹ ji i.

O ni bi ọlọkada naa ṣe tẹ siloo loun yọ aake pelebe jade si i, ko si too ṣẹju peu, Nura ti fa kọkọrọ yọ mọ ọkada rẹ lẹnu, oun si beere pe ko ko iwe ọkada naa fawọn bi ko ba fẹ kawọn ṣa a pa sibẹ.

O lawọn mẹta kan tun gun ọkada ba awọn nibẹ, ṣugbọn nigba ti wọn ri aake ọwọ awọn, wọn ko duro, ọlọkada to si gbe awọn naa ti bẹ lugbẹ, o sa asala fẹmi-in ẹ, eyi lawọn fi ri ọkada rẹ gbe sa lọ.

Nura gun ọkada naa lọ si ile ọrẹ rẹ kan nijọba ibilẹ Guusu Yola, o si tọju ẹ pamọ siibẹ.

Bello loun o mọ pe awo ọrọ naa ti lu, o ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ oṣu yii loun ṣadeede ri awọn fijilante ti wọn waa mu oun, lẹyin naa loun mu wọn lọ sile Nura, ibẹ si lawọn gba wọ gbaga.

Ṣa, iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ yii, wọn ti lawọn mejeeji maa foju bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply