Ọwọ NDLEA tẹ awọn mẹjọ to n gbin igbo l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ajọ to n gbogun ti ẹsun gbigbe ati mimu egboogi oloro, ẹka ti ipinlẹ Ekiti, ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ eeyan mẹjọ kan lori ẹsun pe wọn n gbin igbo. Bakan naa ni wọn ni awọn ti fina si sarè igbo ti ko din ni eeka mẹrin. (4hectres)

Ninu oko igbo didi kan to to iwọn ogun kilomita si ilu Isẹ-Ekiti, nijọba ibilẹ Ọyẹ, ni wọn ti ṣawari ọgbin igbo naa lẹyin ti awọn araalu kan ta wọn lolobo.

Yatọ si eyi, egboogi oloro to to kilogiraamu bii egbeje o le diẹ (1,465 kg) ni Igbakeji oṣiṣẹ ajọ yii nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Kabiru Ibrahim ati Olori eto ati itọpinpin wọn, Ọgbẹni Isaac Fadare, tun gba lọwọ awọn eeyan.

Lakooko akọlu naa, ọna mẹta ọtọọtọ ni ajọ NDLEA ti mu awọn mẹjọ ọhun ninu aginju kan to wa ni Ire-Ekiti, eleyii ti obinrin abilekọ kan wa ninu wọn.

Nigba to n sọrọ ni kete ti awọn oṣiṣẹ ọba naa fina sinu oko igbo ọhun tan, Kabiru Ibrahim sọ pe ọwọ awọn tẹ awọn ọdaran naa pẹlu ifọwọsọwọpọ awọn araalu lẹyin ti wọn ta awọn lolobo pe awọn eeyan kan da oko igbo sinu aginju kan niluu naa.

O sọ pe ni kete ti wọn ta awọn lolobo lawọn lọọ ṣe abẹwo sinu igbo naa, nibi ti awọn ti ri ọna mẹta ọtọọtọ ti wọn gbin in si, ti awọn si fina si i.

Oga awọn NDLEA naa gba awọn eeyan ipinlẹ Ekiti nimọran pe ki wọn lo anfaani ilẹ ọlọraa ti Ọlọrun fun wọn lati gbin ounjẹ ati oun alumọọni miiran ti yoo ṣe ipinlẹ wọn lanfaani.

O fi da wọn loju pe ajọ yii ko ni i yee gbogun ti fayawọ egboogi oloro.

Nigba ti awọn oniroyin n fi ọrọ wa ọkan lara awọn odaran naa lẹnu wo, ọkunrin ẹni aadọta ọdun kan, Ọgbẹni Felix Nwachukwu, ti oun ati ọrẹbinrin rẹ wa lara awọn ti ọwọ tẹ naa sọ pe ọrẹ oun kan to n gbe ni orilẹ-ede Niger lo fi oju oun mọ owo igbo gbingbin naa.

Leave a Reply