Ọwọ NDLEA tẹ Babatunde, oogun oloro lo di sinu apo Sẹmọ bamubamu

Jamiu Abayọmi

Ọwọ ajọ to n gbogun ti gbigbe, tita ati ilokulo oogun oloro lorilẹ-ede yii, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), ti tẹ ọkunrin kan to ti jingiri ninu gbigbe oogun oloro, Suleiman Babatunde Ọba, ni papakọ ofuurufu Muritala Muhammed, niluu Eko, lasiko to fẹẹ wọ ọkọ ofurufu lọ sorileede South Africa.

Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, ti i ṣe Agbẹnusọ ajọ NDLEA lo fọrọ naa lede lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹta, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, nibi to ti fidi ẹ mulẹ pe ọjọ Ẹti, Furaide, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹjọ, to kọja yii, ni ọwọ tẹ ọmọkunrin naa to jẹ ọmọ ẹgbẹ ikọ awọn to n gbogun oloro kan ti wọn mọ nipa ka gbé oriṣiiriṣii ọkan o j’ọkan awọn oogun oloro to maa n yi awọn eeyan lori to si maa n jẹ ki ikun o wu ti wọn ba ti da sinu ọti tabi omi ti wọn n pe ni(Methamphetamine)  lati Naijiria lọ si awọn orileede bii Brazil, Ghana, South Africa, Mozambique ati awọn ilu oke okun mi-in.

Babafẹmi ni, “Asiko to fẹẹ wọkọ ofurufu to jẹ ti Rwanda to n lọ si orileede South Africa, lọwọ ofin ba a pẹlu ọpọlọpọ baagi to di oogun oloro kan ti wọn n pe ni (ephedrine) , rẹpẹtẹ sinu apo Sẹmofita”.

Atẹjade naa fi kun un pe orileede South Africa ni ọkunrin naa n gbe lati bii ogun ọdun sẹyin, iwe irinna ilu naa si wa lọwọ rẹ, ọmọ orileede naa lo fẹ niyawo, o si sọ pe ọmọkunrin kan to n jẹ Hakeem Babatunde toun naa jẹ olugbe South Africa ati ilu Eko ni ọga awọn.

“A tẹsiwaju ninu iwadii wa lori ọmọkunrin naa, a si tẹle e lọ sile ọga rẹ, Salami, to wa  lagbegbe Wosilatu Dawodu, Ijẹṣa, Aguda Surulere, niluu Eko, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹjọ to kọja yii. Ṣugbọn wọn ni ọkunrin yii ti sa kuro niluu lọjọ kan naa tọwọ ba ọmọọṣẹ rẹ yii. Bẹẹ la ba mọto Toyota Venza kan to ni nọmba LSR 410 HT ati Mercedes Benz SUV, to ni nọmba LSD 998 HP ninu ọgba rẹ. Bakan naa la ba ọpọlọpọ foonu ati awọn iwe loriṣiiriṣii ti yoo ran wa lọwọ lori iwadii wa ninu ile naa”.

Ajọ naa kadii ọrọ wọn pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọkunrin naa ati awọn ikọ rẹ ti wọn jọ n ṣiṣẹ ti ko bofin mu ọhun.

Leave a Reply