Ọwọ ofo lawọn aṣoju tijọba ran lọ sorilẹ-ede Niger de pada

Monisọla Saka

Bawọn aṣoju orilẹ-ede Iwọ Oorun Afrika, ti wọn wa labẹ aburada Economic Community of West African State (ECOWAS),  ṣe lọ silẹ Olominira Niger, lati lọọ ṣepade pẹlu olori awọn ologun to ditẹ gbajọba nibẹ ati olori orilẹ-ede ti wọn le kuro nipo, Aarẹ Mohamed Bazoum, lati le mu ohun gbogbo pada bọ sipo ni wọn ṣe pada bọ lai ri ohun to gbe wọn lọ sibẹ ṣe.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni wọn kalẹ si ilu Niamey, ti i ṣe olu ilu orilẹ-ede naa, ṣugbọn ti wọn ko lanfaani ati sun gẹgẹ bi wọn ṣe ti gba a lero, nigba ti ẹkọ ko ti ṣoju mimu.

Olori orilẹ-ede Naijiria nigba kan laye ijọba ologun, Abdulsalami Abubakar, to ko awọn eeyan naa ṣodi lọ si Niger ko sun oorun ọjọ naa nibẹ, nitori Abdourahamane Tiani, ti i ṣe olori awọn ologun to wa lori aleefa bayii ati Mohamed Bazoum, to jẹ aarẹ alagbada ti wọn ko ri ba jokoo ipade pọ.

Aarẹ Tinubu to wa nipo olori ECOWAS bayii ti kọkọ paṣẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọgbọnjọ, oṣu Keje, pe kawọn ọmọ ogun ri i daju pe awọn da Bazoum pada sipo Aarẹ to wa laarin ọsẹ kan pere. Ṣugbọn to jẹ pe tijatija lọkan lara awọn ọmọ ogun ti wọn ditẹ gbajọba naa fi fesi ninu atẹjade ti wọn ka seti gbogbo ilu naa lori ikanni tẹlifiṣan ilẹ Niger, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ yii. Wọn ni kawọn ikọ ECOWAS ma dan an wo pe awọn yoo fi ọmọ ogun koju awọn, nitori ọrọ naa yoo lagbara, yoo si la ogun lọ.

“Ibinu yoowu tabi gbigbero lati waa fi ikanra kogun ja ilẹ Niger labẹ ijọba ologun yii ko ni i rọrun, nitori loju-ẹsẹ, lairotẹlẹ, ni wọn yoo ri ọwọja awọn ọmọ ogun ilẹ Niger, lọdọ orilẹ-ede yoowu laarin awọn ti wọn para-pọ ọhun”.

Ṣaa, awọn aṣoju ti wọn ran lọ ti dari pada de, ṣugbọn bi wọn ṣe lọ ni wọn ṣe bọ.

 

Leave a Reply