Ọwọ ọlọpaa tẹ awọn janduku oloṣelu mẹẹẹdọgbọn lasiko idibo

Monisọla Saka

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kede pe awọn afurasi mẹtalelogun kan to ṣee ṣe ki wọn jẹ janduku oloṣelu ti wọn n da awọn ibudo idibo ru, ti wọn si tun huwa arufin mi-in lasiko ti eto idibo n lọ lọwọ, ni ọwọ awọn ti tẹ lasiko eto idibo aarẹ ati tawọn aṣofin, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, nipinlẹ Eko.

Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundenyin, to fidi ọrọ naa mulẹ fun ileeṣẹ iroyin ilẹ wa, NAN, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, sọ pe iye awọn afurasi to wa lakata awọn tun le ju iye tawọn fi sita bayii lọ pẹlu bi ọwọ awọn ṣe tun tẹ awọn mi-in lawọn ibudo idibo kaakiri lọjọ Abamẹta, Satide, ati pe awọn ti bẹrẹ si i ṣe akojọ iye wọn.

Tẹ o ba gbagbe, awọn gidigannku atawọn agbebọn kan ya wọ awọn ibudo idibo lagbegbe Mafoluku, Oshodi atawọn agbegbe mi-in nipinlẹ Eko, wọn si da eto idibo ibẹ ru lẹyin ti wọn dana sun gbogbo awọn iwe idibo tawọn eeyan ti tẹka si, ti wọn si tun da wahala silẹ.

Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, CP Idowu Owohunwa, ṣalaye fawọn oniroyin pe ọpọlọpọ awọn agbegbe kan nipinlẹ Eko lawọn ẹni ibi ọhun ti fa ijangbọn.

O ni bo tilẹ jẹ pe ọwọ ti ba awọn kan ninu wọn, nigba tawọn ba pari gbogbo iwadii to yẹ tan lawọn yoo sọ iye awọn janduku afurasi ọdaran ti wọn wa lakata awọn fawọn araalu.

 

Leave a Reply