Ọwọ ọlọpaa tẹ awọn to n wa kusa lọna aitọ ni Kwara

 

Ibrahim Alagunmu Ilọrin

O kere tan, awọn afurasi mẹjọ kan ni ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara tẹ pe wọn n wa kusa lọna aitọ. Lara wọn ni Abdulbagi Sadiq, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, ti wọn mu pẹlu tirela to ni nọmba SGM 222 ZR, Isah Amisu, ẹni ọdun mejidinlọgbọn, pẹlu tirela to ni nọmba GBE 347ZE, Mohammed Zanihat Idris, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, pẹlu tirela to ni nọmba BWR 151 YL, Alhassan Rabiu, Mohammed Abdulbagi  Ibrahim Sule Balarab, Mohammed Dalhatu Idris ati Abubakar Tasiu, l’Opopona Share, Tsaragi, nijọba ibilẹ Patigi, nipinlẹ naa.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ niluu Ilọrin, lo ti sọ pe ọwọ tẹ awọn afurasi naa lẹyin ti awọn olugbe Patigi, nijọba ibilẹ Patigi, kọ iwe ẹsun si Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, CP Paul Odama psc (+), pe awọn afurasi ọdaran kan maa n wa kusa lagbegbe naa lọna aitọ. Eyi lo mu ki ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ iwadii, tọwọ fi tẹ awọn afurasi naa.

Ajayi ni awọn eeyan naa jẹwọ pe loootọ lawọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn. A gbọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti wọ gbogbo wọn lọ sile-ẹjọ, bẹẹ ni wọn ti ko gbogbo ẹru ofin ti wọn ba lọwọ wọn lọ si olu-ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara.

 

 

Leave a Reply