Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi pampẹ ofin gbe ọkunrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Gbenro lori ẹsun pe o fun iyawo rẹ, Wayeṣọla, lọrun pa.
Iṣẹlẹ yii ni wọn lo waye laduugbo kan ti wọn n pe ni Salvation Army, Odojọmu, niluu Ondo, laaarọ kutukutu ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja.
Ninu alaye ti ọkan ninu awọn ọmọ oloogbe ọhun, Foyekẹ ṣe fun wa, o ni o da oun loju daadaa pe Gbenro to jẹ baba oun lo pa obìnrin to ku ọhun.
Ọmọdebinrin ẹni ọdun marun-un ọhun ni ilẹ ti n mọ diẹdiẹ lọjọ ti iṣẹlẹ yii waye, o ni ṣe loun ni ki oun sare yọju sawọn obi oun ninu yara tí wọn sun si lasiko ti oun fẹẹ lọọ tọ nita gbangba ile awọn.
Ọmọ yii ni ṣe loun ba baba oun lori iya oun to fun un lọrun dan-in dan-in mọ ori bẹẹdi nigba toun silẹkun yara ti awọn mejeeji sun si.
Bo ṣe fẹẹ sa jade lati bẹbẹ fun iranlọwọ awọn araadugbo ni baba rẹ fa a pada, to si kílọ fun un pe pipa loun maa pa a to ba fi le pariwo sita.
Lẹyin-o-rẹyin lo ni oun ri iya oun ti wọn da aṣọ bo lori ti ọkọ rẹ to lu u pa naa si jokoo ti i sori bẹẹdi.
Ọrọ ti ẹgbọn ọkọ oloogbe, Ọgbẹni Adebisi Adebusoye, sọ fun wa ko fi bẹẹ yatọ si ti Foyekẹ to jẹ ọmọ rẹ.
O ni aarin aago marun-un si mẹfa idaji ni ẹnikan pe oun sori aago pe Wayeṣọla aburo oun ti ku, loju ẹsẹ lo ni oun ti mura lati lọ sile wọn ko le fidi ohun to gbọ naa mulẹ.
O ni oun si ba ọkọ aburo oun to jokoo ti oku iyawo rẹ lori bẹẹdi ninu yara nigba toun de ile wọn, lẹyin to gbọ aṣiri oun to ṣẹlẹ lati ẹnu ọmọ rẹ lo pasẹ pe ki wọn tilẹkun mọ awọn mejeeji, to si tete lọọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa tesan Ẹnuọwa to wa niluu Ondo leti.
ALAROYE gbọ lati ẹnu araadugbo kan to jẹ ọrẹ Oloogbe Wayeṣọla, o ni alẹ Ọjọbọ, Tọsidee, lo ṣẹṣẹ de lati oko latari ọrẹ rẹ kan to fẹẹ waa ba ṣe inawo lọjọ Ẹti, Furaidee.
Ọdọ ọrẹ rẹ to n ṣe inawo lo ni o yẹ ko sun lọjọ naa, ṣugbọn ọkọ rẹ to wa nile lo fi pinnu ati waa sun sile wọn.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, ni iwadii awọn si n tẹsiwaju lori rẹ.