Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ awọn ọkunrin meji kan, Peter Monday Afodewu, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, ati Jamiu Kadiri, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, lori ẹsun igbiyanju lati paayan ati idigunjale.
ALAROYE gbọ pe nibi ayẹyẹ ọdun Ọṣun Oṣogbo to waye lọjọ kọkanla, oṣu Kẹjọ yii ni Jamiu ati Peter pẹlu awọn ti wọn jọ n jale ti hùwà laabi naa.
Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣe sọ, awọn kan ti wọn wa sibi ayẹyẹ naa lati ilu Iwo ni wọn lọọ to fi to awọn ọlọpaa agbegbe Ọja-Ọba, leti pe awọn kan ti gba ọkada ti awọn gun wa.
Ọpalọla ṣalaye pe awọn adigunjale naa gun ọkan lara awọn ti wọn gba ọkada Bajaj rẹ ni nnkan lẹyin ọrun, to si jẹ pe ori lo ko o yọ.
O ni awọn ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ loju ẹsẹ, wọn fi iṣẹlẹ naa to gbogbo awọn agọ ọlọpaa ti wọn wa kaakiri leti lati maa ṣọ ẹnikẹni ti wọn ba fura si.
Ko pẹ ni ọwọ tẹ Jamiu ati Peter nigba ti wọn n lọ siluu Eko pẹlu ọkan lara awọn ọkada naa lasiko ti awọn ọlọpaa agbegbe Oke-Baalẹ lọ sọna ilu Awo nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ.
Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe wọn ba ọkada Bajaaj kan ti ko ni nọmba lọwọ awọn mejeeji, bẹẹ ni wọn ba ọbẹ kan, daga kan, fila to ni ami idanimọ ẹgbẹ OPC ati kaadi idanimọ ẹgbẹ OPC pẹlu ọpọlọpọ oogun.
O ni ti iwadii ba ti pari ni awọn mejeeji yoo foju ba ile-ẹjọ.