Ọwọ ọlọpaa tẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun to fun obinrin mẹwaa loyun

Monisọla Saka

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ ọkunrin ọmọ ọdun mẹtadinlogun (17) kan, Noble Uzuchi, fun ẹsun pe o fun awọn obinrin mẹwaa loyun lẹẹkan naa nipinlẹ Rivers.

Ninu atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Grace Iringe-Koko, fi lede lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni wọn ti ṣalaye pe, wọn fi panpẹ ofin gbe afurasi yii ati ọkan ninu awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ ibi wọn, Chigozie Ogbona, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29).

Awọn agbofinro fidi ẹ mulẹ pe awọn afurasi mejeeji yii atawọn obinrin meji mi-in, Favour Bright, ẹni ọgbọn ọdun (30), ati Peace Alikoi, ẹni ogoji ọdun (40), ni wọn da okoowo buruku ti wọn ti n ta ọmọ silẹ lawọn ijọba ibilẹ Obio/Akpor ati Ikwerre, nipinlẹ naa.

Iringe tẹsiwaju pe iwadii fi han pe, nigba tawọn obinrin to lugbadi awọn eeyan yii ba ti bimọ inu wọn tan, olori awọn ikọ yii yoo fun wọn ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira(500,000), wọn yoo si ta ọmọ tuntun ti wọn bi yii fawọn kan. Gbogbo awọn ọmọ ti wọn ti bi sẹyin tẹlẹtẹlẹ ninu ile ti wọn ti n ṣiṣẹ ibi yii ni wọn ti ta.

O ni, ” Ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ku iṣẹju marundinlogun lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ keje, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, lawọn kan ta ikọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ipinlẹ Rivers, C41 Intelligence, lolobo nipa iṣẹ buruku ti wọn n ṣe yii, ni awọn agbofinro ba ya lọ si awọn ile meji kan laduugbo Igwuruta ati Omagwa, nijọba ibilẹ Obio/Akpor ati Ikwerre, nibi ti wọn sọ pe wọn ko awọn ti wọn n lo lati fi ṣiṣẹ owo ọmọ tuntun pamọ si, lati lọ gbọn ọn yẹbẹyẹbẹ. Ṣaaṣa ni ẹni ti ko loyun sinu ninu awọn eeyan mẹwaa tawọn ọlọpaa ribi doola lasiko ti wọn lọọ ka wọn mọbẹ”.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Rivers sọ pe lasiko tawọn ọlọpaa lọọ ka wọn mọ ileeṣẹ ti wọn da silẹ yii, ni wọn doola awọn aboyun mẹwaa ti wọn ba lakata wọn, ti wọn si tun fofin gbe afurasi meji ti wọn jẹ olori ati oludasilẹ ileeṣẹ ọhun.

O tẹsiwaju pe, “Gbogbo awọn obinrin tawọn agbofinro ribi ko jade kuro nibẹ ni wọn jẹwọ pe niṣe ni wọn tan awọn wọnu iṣẹ buruku ti wọn ti n ta ọmọ yii, nitori bawọn ṣe nilo owo lati fi yanju awọn adojukọ ati bukaata kan to yọju.

Bakan naa ni awọn agbofinro tun gba ọkọ ayọkẹlẹ Honda Pilot SUV funfun kan lọwọ olori awọn oniṣẹ ibi naa”.

Iringe fi kun un pe, Arabinrin Favour ati Peace ti wọn jẹ olori ileeṣẹ yii gan-an ni wọn haaya Uzuchi ati Ogbonna, lati maa ko ibasun gidigidi fawọn obinrin naa ki wọn baa le tete loyun. O ni wọn ti taari ọrọ naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn ti n ṣewadii iwa ọdaran SCID, ẹka ti ipinlẹ Rivers. O fi kun un pe iwadii ṣi n lọ lọwọ, gbogbo ipa lawọn yoo si sa lati tọpinpin, kawọn si ri awọn ti wọn n ra awọn ọmọ tuntun ti wọn ti ta sẹyin tẹlẹ mu.

Leave a Reply