Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Kọmiṣanna ọlọpaa Ekiti, CP Tunde Mobayọ, ti kede pe ara obinrin ọlọpaa tibọn ba lasiko atundi ibo to waye niluu Omuo-Ekiti lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, ti n ya nileewosan ti wọn ti n tọju ẹ.
Rogbodiyan to da wahala yii silẹ yii lo waye lasiko ti wọn n dibo fun ipo aṣofin ẹkun idibo Ila-Oorun Ekiti lẹyin iku Ọnarebu Juwa Adegbuyi, eeyan mẹta lo si dagbere faye, nigba tawọn mi-in farapa.
Mobayọ ṣalaye pe ko si ootọ ninu iroyin to n lọ kaakiri lati ọjọ iṣẹlẹ naa pe ọlọpaa-binrin ọhun dagbere faye nitori bo tilẹ jẹ pe ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun lo wa, itọju to n gba ti n yọri si rere.
Bakan naa lo kede pe afurasi mẹta lọwọ ti tẹ lori ọrọ naa, awọn agbofinro lo si lọọ mu wọn nibi ti wọn sapamọ si, bẹẹ ni wọn wa ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Ado-Ekiti.
O waa ṣeleri pe gbogbo awọn to lọwọ si ipaniyan ati rogbodiyan to waye naa ni wọn yoo foju wina ofin.
Ẹwẹ, ajọ eleto idibo (INEC) ti sun ibo naa siwaju di ọjọ mi-in. Adari ajọ naa l’Ekiti, Ọmọwe Tella Adeniran, lo sọ eleyii di mimọ pẹlu alaye pe bi ajọ naa ṣe n gbiyanju lati ṣeto idibo to dangajia, o han gbangba pe awọn kan ko ti i setan fun alaafia nilẹ yii.
Bakan naa ni Gomina Kayọde Fayẹmi, Oloye Ṣẹgun Oni, Ayọdele Fayoṣe atawọn mi-in ti bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yii.
Bi Fayẹmi ṣe koro oju si wahala ọhun to si ni dandan ni kawọn ọlọpaa mu gbogbo awọn to lọwọ si i ni Oni bẹnu atẹ lu iwa jagidijagan naa, to si fagi le gbogbo eto ipolongo ẹ lati bu ọla fun awọn ti nnkan ṣẹlẹ si, ṣugbọn Fayoṣe naka aleebu si ẹgbẹ All Progressives Congress (APC) pẹlu ẹsun pe wọn mọ-ọn-mọ maa pa araalu nitori wọn ti kẹyin sijọba wọn.