Ọwọ pada tẹ Tosin, olori ọmọ ẹgbẹ okunkun to n yọ wọn lẹnu n’Igbọkọda

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ọmọ ogun oju-omi nipinlẹ Ondo, ti fi pampẹ ofin gbe afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan, Tosin Wanlele, ti wọn lo n yọ awọn eeyan Igbọkọda  lẹnu.

Olori awọn ikọ ọmọ ogun naa, Wasuku Alushi, lo fidi eyi mulẹ fawọn oniroyin lasiko to n ṣe afihan afurasi ọhun ni olu ileeṣẹ wọn to wa niluu Igbọkọda, nijọba ibilẹ Ilajẹ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kọkanla, ọdun yii.

Alushi ni ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejila, oṣu yii, lọwọ awọn tẹ Tosin to jẹ ọga patapata fawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n daamu awọn araalu.

O ni gbogbo igba lọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun ọhun atawọn ẹmẹwa rẹ maa n da awọn eeyan lọna pẹlu awọn nnkan ija oloro, kọwọ awọn ọmọ ogun oju omi too pada tẹ ẹ laipẹ yii.

Ọkunrin naa ni awọn ti fi Tosin ṣọwọ si ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, ẹka ti ipinlẹ Ondo, ki wọn le gbe igbesẹ to yẹ lori ọrọ rẹ.

Alushi ni gbogbo igba lawọn ọmọ ogun n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo yooku lati ri i pe iwa ọdaran dinku nipinlẹ Ondo, paapaa lawọn ilu to wa lagbegbe omi.

 

Leave a Reply