Owo tawọn obi ọmọ ti mo ji gbe fun mi ko to nnkan ni mo ṣe fun un lọrun pa -Abubarkar

Adewale Adeoye

Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Adamawa ti sọ pe ọdọ awọn ni ọdaran kan, Abubarkar Kawu, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (39), kan ti wọn mu fẹsun iwa ọdaran meji ọtọọtọ wa, ati pe, gbara tawọn ba ti pari gbogbo iwadii awọn lawọn yoo foju rẹ bale-ẹjọ.

ALAROYE gbọ pe ṣe ni Abubarkar ji Abdulhafiz Buba Aliyu, ọmọ ọdun mẹfa kan gbe, to si n beere fun miliọnu mẹta aabọ Naira lọwọ baba ọmọ naa ko too di pe yoo ju ọmọ naa silẹ ko le maa ba tiẹ lọ layọ ati alaafia.

Ṣugbọn Ọgbẹni Muhammed Buba Aliyu ti i ṣe baba ọmo naa sọ pe ko sowo to to bẹẹ lọwọ oun rara. Ẹgbẹrun lọna aadọta Naira pere ni baba ọmọ naa fi n bẹ Abubarkar, ṣugbọn niṣe ni inu owo naa n bi i gidi pe owo iranu gbaa ni wọn fi n bẹ oun lori akọ iṣe toun ṣe ko too di pe oun ri ọmo naa ji gbe.

Nigba ti baba ọmo ọhun ko tete ṣe ifẹ inu Abubarkar, ti ko si ri gbogbo ọna lati ri miliọnu mẹta aabọ Naira gẹgẹ bii owo to n beere fun lọwọ baba ọmo naa ni Abubarkar ba kuku fun ọmọ ọhun lọrun pa patapata, to si lọọ ju oku rẹ sinu igbo kan ko too di pe ọwọ awọn ọlọpaa to ti gbọ si iṣẹlẹ naa tẹlẹ tẹ ẹ.

Alukoro ileeṣẹ awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Suleiman Yahaya Nguroje, sọ pe, ‘Iṣẹ alagbafọ ni Abubarkar n ṣe, ko too gbero lati hu iwa ọdaran naa. Ṣe lọ lọọ ji Abdulhafiz Buba Aliyu, ọmọ ọdun mẹta kan gbe, to si n beere fun miliọnu mẹta aabọ naira lọwọ baba ọmọ naa, ṣugbọn ẹgbẹrun lọna aadọta Naira pere ni Muhammed Aliyu sọ pe o wa lọwọ oun, ti inu si bi Abubarkar pe ọwo radarada lo fi n bẹ oun yii, o fun ọmọ naa lọrun pa nibi to tọju rẹ si, o si lọọ ju oku rẹ  sinu igbo kan, ko too di pe ọwọ ọlopaa tẹ ẹ. O ti jẹwọ gbogbo bo ti ṣe ri ọmo naa ji gbe fawọn ọlọpaa bayii’

Leave a Reply