Florence Babaṣọla
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe afurasi meji lọwọ ti tẹ lori wahala iṣekupani miiran to ṣẹlẹ niluu Mọdakẹkẹ lopin ọsẹ to kọja yii.
Abule Alapata, niluu Mọdakẹkẹ, lawọn agbebọn ti pa awọn agbẹ meji lọjọ Abamẹta, Satide to kọja, labule naa ti ko jinna si Toro, nibi ti wọn ti pa awọn marun-un nipakupa lọsẹ meji sẹyin.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ fun ALAROYE pe ni kete ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lawọn ti bẹrẹ iṣẹ, afurasi meji lo si ti wa lakolo awọn latari iṣẹlẹ naa.
Gẹgẹ bi aṣaaju kan niluu Mọdakẹkẹ, Fẹmi Eluyinka, ṣe sọ, eeyan mẹrin ni awọn agbebọn naa kọkọ ko labule Alapata lọjọ Satide to kọja ọhun lasiko ti wọn n ṣiṣẹ ninu oko wọn.
Eluyẹra ṣalaye pe, “Ọkan lara awọn ti wọn ji gbe naa to raaye sa mọ wọn lọwọ lo wa sinu ilu waa sọ nnkan to ṣẹlẹ fun wa, awa naa si lọọ fi iṣẹlẹ naa to DPO agbegbe Mọdakẹkẹ leti.
“DPO yii lo ko awọn eeyan rẹ pẹlu awọn ọdọ lọ sagbegbe naa, wọn si ri oku awọn agbẹ meji; ọkunrin kan ati obinrin kan, a ti gbe wọn lọ si ile igbokuu-si ti OAUTHC.
“Nigba to ya ni wọn sọ fun wa pe obinrin kan tun jajabọ lọwọ awọn agbebọn yii, ṣugbọn wọn ti ṣe e leṣe lọwọ. Wọn mu un lọ si aafin Ogunṣua, ko too di pe a mu un lọ sileewosan, nibi to ti n gbatọju bayii.
“Lọwọlọwọ bayii, a ṣi n wa ẹnikan to ku, ṣugbọn gbogbo agbegbe wa wa lalaafia nitori a ti ba awọn eeyan wa sọrọ lati jẹ ki awọn agbaagba wa pe apero lori iṣẹlẹ naa, ki wọn si wa ojutuu si i.”
Amọ ṣa, Ọpalọla sọ pe Kọmiṣanna ọlọpaa, Wale Ọlọkọde, ti ṣidii lọ si agbegbe naa lati daabo bo ẹmi ati dukia awọn eeyan ibẹ.