Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti mu eeyan mẹta ti wọn jẹ oṣiṣẹ nibudo iwakusa kan lori iku to pa ọkunrin agbẹ kan lagbegbe Ibẹrẹkodo, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Atakumọsa, nipinlẹ Ọṣun.
Oloogbe naa, ẹni ti wọn pe orukọ rẹ ni Ajewọle, ni wọn sọ pe o ku lẹyin ti ija bẹ silẹ laarin oun atawọn lebira ti wọn deede wọnu oko rẹ lati wa kusa lai gba aṣẹ lọwọ rẹ.
Gẹgẹ bi ẹnikan to n gbe ni Iberekodo ṣe sọ, Ajewọle yari kanlẹ pe awọn awakusa naa ko le gba ilẹ oun lọwọ oun, nigba ti wahala naa si pọ ni wọn yinbọn pa a.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe eeyan mẹta lọwọ ti tẹ lori iṣẹlẹ naa.
Ọpalọla ṣalaye pe loootọ ni wọn pa ọkunrin naa, awọn ọlọpaa si ti n fi ọrọ wa awọn afurasi mẹtẹẹta ti wọn mu lẹnu wo lori ohun ti wọn mọ si i.
O ni awọn yoo ri i pe idajọ ododo fẹsẹ mulẹ lori ọrọ naa.