Adewale Adeoye
Ọdọ awọn ọlọpaa ni Eleweeran, niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, ni Ọgbẹni Akeem Usman wa, nibi to ti n ran wọn lọwọ lori iwadii ti wọn n ṣe lati le fọwọ ofin mu gbogbo awọn onibaara rẹ gbogbo to n ta awọn ẹya ara oku fun, pataki ju lọ, ti ọmọ ileewe Fasiti ‘Ọbafẹmi Awolọwọ University’ (OAU) kan, Oloogbe Quadry Salami, to pa danu laipẹ yii, to si ta awọn ojulowo ẹya ara rẹ fawọn oniṣẹ ibi kan.
ALAROYE gbọ pe Alagba Salami ti i ṣe baba Quadry lo lọọ fẹjọ sun awọn ọlọpaa agbegbe Kenta, niluu Abẹokuta, lọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii, pe oun n wa ọmọ oun, Quadry, to jẹ akẹkọọ onipele akọkọ 100 level nileewe ‘Ọbafẹmi Awolọwọ University,’ (OAU). Baba naa ṣalaye fawọn ọlọpaa pe lati ọjọ kẹjọ, oṣu Kọkanla, ọdun yii loun ti foju kan an gbẹyin, o loun pe gbogbo foonu rẹ, ko lọ, lawọn ọlọpaa ba bẹrẹ iṣẹ lori ọrọ ọhun.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Ọmọlọla Odutọla, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kejila, sọ pe funra ọga ọlọpaa patapata nipinlẹ Ogun, C.P Abiọdun Alamutu, lo ṣaaju ikọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ agbegbe ‘Mile 6’, to wa niluu Ajebọ, lati lọọ fọwọ ofin mu Akeem Usman, lẹyin ti ohun ti wọn fi n wa foonu oloogbe naa tọka si i pe ọwọ rẹ lo wa. Wọn gba a mu, o si mu wọn lọ sibi to sinku oloogbe naa si.
Akeem yii lo tọka si oniṣegun kan, Ọgbẹni Ifadowo Niyi, to pe ni ọrẹ rẹ. Nigba ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo lo jẹwọ fawọn ọlọpaa pe oun pẹlu Ifadowo lawọn jọọ pin ẹya ara oloogbe naa fun oogun owo.
Alukoro ni, ‘‘Akeem ti jẹwọ fawọn ọlọpaa, ohun to sọ ni pe oun pẹlu Ifadowo lawọn jọ pa oloogbe naa, tawọn si pin ẹya ara rẹ, ori oloogbe naa ati ọrun ọwọ rẹ mejeeji ni Ifadowo ko lọ, o si san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira sinu akaunti Akeem.
‘‘Lẹyin naa ni Akeem n ta awọn ẹya ara oloogbe naa lẹyọkọọkan fawọn eeyan to nilo rẹ lati fi ṣoogun Awure. Lopin ohun gbogbo, Akeem lọọ ri iyooku mọlẹ nigba ti ko wulu fun un mọ.
‘‘Koda awọn mejeeji ti tun jẹwọ fawọn ọlọpaa pe ki i ṣe oloogbe yii lawọn maa kọkọ pa, wọn ni awọn ti figba kan pa awọn mẹrin kan sẹyin, tawọn si ti fori wọn ṣetutu Oṣolẹ’’.
Ni ipari ọrọ rẹ, Alukoro ni ọga ọlọpaa patapata nipinlẹ Ogun ti loun ko ni i foju to daa wo awọn ọdaran gbogbo ti wọn fẹẹ sọ ipinlẹ Ogun di ibugbe wọn, afi ki wọn yaa kuro lagbegbe naa lo le pe wọn.