Ọwọ tẹ alaga ẹgbẹ awakọ pẹlu awọn ohun eelo idibo abẹle l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Nibi to ti n ṣeto ayederu iforukọ silẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ All Progressive Congress kan nile rẹ to wa niluu Ondo ki wọn le lanfaani ati kopa ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu ọhun to fẹẹ waye lọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lọwọ ti tẹ alaga ẹgbẹ awakọ nigba kan ri nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Ariyọ Ajirọba.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, lo fidi eyi mulẹ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Ọdunlami ninu atẹjade rẹ ni, ‘‘Awọn eeyan kan ni wọn waa yọ sọ fawọn ọlọpaa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii pe awọn kofiri ọga awọn awakọ tẹlẹri ọhun nibi to ti n funra rẹ forukọ awọn eeyan silẹ gẹgẹ bii ojulowo ọmọ ẹgbẹ APC ninu ile rẹ to wa niluu Ondo.

O ni lọgan lawọn agbofinro lati teṣan Yaba, ti ti gbera, ti wọn si mọna ile ọkunrin naa pọn, ti wọn si ba oun ati ẹnikan nibi ti wọn ti n funra wọn forukọ ọpọlọpọ awọn eeyan silẹ loootọ.

Awọn nnkan to ni awọn ba nikaawọ ọkunrin tọwọ tẹ ọhun ni: iwe nla kan ti wọn fi n forukọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC silẹ, ọpọlọpọ orukọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lati Wọọdu keje, niluu Ondo, fọto pasipọọtu awọn eeyan mẹtalelaaadọta, iwe akọsilẹ kan pẹlu ọpọlọpọ orukọ ti wọn to sinu rẹ, bigi nooti meji to kun fọfọ fun orukọ ati nọmba foonu awọn eeyan pẹlu fọọmu iforukọsilẹ meji.

Ọdunlami ni awọn meji ti awọn fi pampẹ ofin gbe ṣi wa lọdọ awọn, ti awọn si n fọrọ wa wọn lẹnu wo lọwọ lati mọ ẹni ti wọn n ṣiṣẹ fun atawọn ẹgbẹ wọn yooku ti wọn jọ huwa to lodi sofin naa.

O ni Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abayọmi Ọladipọ, n fi asiko yii kilọ fawọn oloṣelu ki wọn tete kilọ fawọn alatilẹyin wọn lati yago fun awọn iwa to lodi labẹ ofin, nitori awọn ọlọpaa ko ni i kawọ gbera maa woran ki awọn ọdaran kan maa huwa to le mu ifasẹyin ba eto oṣelu awa-ara-wa to wa lode.

 

Leave a Reply