Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Bi eeyan ba mọ nnkan an tọju, ko ranti ẹni to mọ ọn wa. Bẹẹ gẹlẹ lọrọ ri fun awọn awọn oniṣowo igbo meji kan, Aminu Saudi, ẹni ọdun marundinlaaadọta ati Abdulahi Sani, ẹni ọdun marundinlogoji tọwọ ajọ to n gbogun ti lilo ati gbigbe oogun oloro lorilẹ-ede yii (NDLEA), tẹ niluu Ọgbẹsẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, pẹlu ọpọlọpọ igbo ti wọn ko sinu irẹsi.
Alukoro fun ajọ ọhun, Fẹmi Babafẹmi, lo fidi eyi mulẹ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii.
Babafẹmi ni inu apo irẹsi lawọn afurasi naa ko igbo ọhun pamọ si, ki wọn le fi tan awọn agbofinro jẹ pe irẹsi tootọ lo wa ninu apo naa, ki i ṣe igbo. Igbo ti wọn ba ni ikawọ awọn eeyan naa gẹgẹ bi ọkunrin naa ṣe sọ to bii igba ati mọkanla kilogiraamu (211 kg)
O ni awọn araalu kan lo ta awọn oṣiṣẹ ajọ naa lolobo ti wọn fi ri awọn onigbo mejeeji ọhun mu l’Ọgbẹsẹ.
O ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin yii, kan naa lawọn tun ṣawari oko igbo to to bii sare ilẹ mẹfa ninu igbo kijikiji kan niluu Uṣo, nijọba ibilẹ Ọwọ.
Babafẹmi ni awọn ti dana sun oko ọhun, ti awọn si ri i daju pe gbogbo rẹ di eeru ki awọn too kuro nibẹ.