Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti tẹ awọn afurasi ajinigbe to yinbọn pa Ọgbẹni Gbenga Owolabi, ẹni to ṣẹṣẹ de latilẹ Amẹrika ati akẹkọọ Fasiti Ladoke Akintọla University of Technology, LAUTECH, Ogbomọṣọ, lẹyin ti wọn ji wọn gbe.
Mẹta lawọn afurasi ajinigbe ọhun, ọmọ baba kan naa si ni wọn. Orukọ wọn ni Namaru Abubakar, Saliu Abubakar ati Usman Abubakar.
Ọkunrin darandaran kan to n jẹ Alhaji Waheed Hammed ni wọn tun lọọ ji gbe labule Adafila, lagbegbe Ogbomọṣọ kan naa tọwọ palaba wọn fi segi lọtẹ yii.
Nigba to n ṣafihan awọn afurasi ọdaran naa fawọn oniroyin n’Ibadan l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kejila, ọdun yii, Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, to sọrọ lorukọ ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Adebọwale Williams, fidi ẹ mulẹ pe ni kete ti wọn fi iṣẹlẹ yii to awọn leti loun ti gbe ikọ awọn ọlọpaa alagbara kan dide lati tọpinpin iṣẹlẹ naa.
Awọn atọpinpin ọhun, pẹlu iranlọwọ awọn ọdẹ ibilẹ atawọn fijilante ni wọn ya lu awọn afurasi ajinigbe wọnyi nibuba wọn, ti wọn mu awọn ọbayejẹ eeyan naa, ti wọn si tu Alhaji Waheed to wa ninu igbekun wọn silẹ lai fara pa.
“Awọn afurasi ajinigbe yii ni wọn fẹnu ara wọn jẹwọ pe awọn lawọn ji ọga ileetura gbe niluu Ogbomọṣọ laipẹ yii, ti awọn si yinbọn pa a”.
SP Oṣifẹṣọ ṣalaye siwaju pe “Nibi ti wọn ti n halẹ mọ Alhaji Waheed pe ko tete ba awọn ẹbi ẹ sọrọ lati gbe owo nla ranṣẹ si awọn bi ko ba fẹ ki awọn yinbọn pa a danu gẹgẹ bi awọn ṣe pa baba to ni ileetura Tana, niluu Ogbomọṣọ, laṣiiri wọn ti tu”.
Tẹ o ba gbagbe, igba mẹta ọtọọtọ lawọn ajinigbe pitu ọwọ wọn lagbegbe Ogbomọṣọ laarin oṣu kan pere ninu ọdun 2022 yii nikan ṣoṣo.
Ọgbẹni Christpoher Bakare, ẹni to jẹ alamoojuto oko Oloogbe Christpoher Adebayọ Alao-Akala, ti i ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri ni wọn kọkọ ji gbe lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrindilogun, oṣu Keje, ọdun yii.
Lẹyin naa, iyẹn lọjọ Jimọ, ọjọ kejilelogun, oṣu Keje, ọdun yii, ni wọn ji ọkunrin kan ti wọn n pe ni Baba Rasheed, oludasilẹ ileewosan aladaani kan to wa niluu Ogbomọṣọ bakan naa gbe.
Lara awọn ti wọn tun ji gbe ni oludasilẹ ileewosan kan, oludasilẹ ileetura kan pẹlu alamoojuto oko Oloogbe Christpoher Adebayọ Alao-Akala, ti i ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri.
Lọjọ keji, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 yii, ni wọn lọọ ka
oludasilẹ ileetura Tana Hotel to wa labule Aba, niluu Ogbomọṣọ, mọ iletura naa, ti wọn si ji oun pẹlu ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ẹ to n jẹ Ọpadele Rachael gbe.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, bii igba ti ọrẹ ati ọrẹ ba n sin ara wọn lọ loju titi lawọn ainingbe naa n mu awọn mejeeji ti wọn ji gbe ọhun lọ titi ti wọn fi mu wọn lọ raurau.
Akẹkọọ ọlọdun to gbẹyin ni Ladoke Akintola Universy of Technology, LAUTECH, niluu Ogbomọṣọ, lọmọbinrin to n jẹ Rachael yii.
Lọjọ kẹta ti wọn ji awọn eeyan naa gbe lawọn ọbayejẹ eeyan ọhun bẹrẹ idunaadura lori ẹrọ ibanisọrọ pẹlu awọn idile Ọgbẹni Owolabi.
Ṣugbọn lẹyin ti awọn ọdaju eeyan wọnyi gba miliọnu marun-un Naira lọwọ awọn ẹbi oloogbe naa ni wọn yinbọn pa oun pẹlu oṣiṣẹ ẹ ti wọn ji gbe.
Pabanbari iwa ailaaanu ti awọn eeyan yii hu ni pe wọn tun yinbọn pa Idowu Ajagbe, ọlọkada ti awọn ẹbi Oloogbe Owolabi ran lati lọọ gbe owo ọhun fun wọn.
Iwadii ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe o ku ọla ti Ajagbe maa kan ile ẹ, to si tun jẹ deede ọjọ to maa ṣe ayẹyẹ ogoji (40) ọdun to delẹ aye lawọn adaniloro ọhun yinbọn pa a. Lọjọ kẹta iku ẹ ni wọn ṣẹṣẹ kan ile naa pẹlu awọn eroja to ti fowo ara ẹ ra silẹ ki wọn too pa a.
Iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ọrọ awọn ọmọ iya mẹta ti wọn n ṣiṣẹ ajinigbe yii gẹgẹ bi SP Ọṣifẹṣọ ṣe fidi ẹ mulẹ lorukọ CP Williams ti i ṣe ọga awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ.