Ọwọ tẹ awọn ayederu dokita ayẹjẹ-wo mẹta l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Ọṣogbo

Titi igba ti a n kọ iroyin yii, inu gala awọn agbofinro lawọn kọsọngbo ti wọn n pe ara wọn ni aṣayẹwo-ẹjẹ kaakiri ipinlẹ Ọṣun wa, ireti si wa pe latibẹ ni wọn yoo ti dero kootu, bẹẹ ni awọn ibudo mẹrin ti ko bofin mu ti wọn ti n ṣayẹwo ẹjẹ ti wa ni titi pa patapata.

Ajọ to n ṣe iforukọsilẹ, to n si n ṣakoso awọn ibudo ti wọn ti n ṣayẹwo ẹjẹ lorileede yii, Medical Laboratory Scientist Council in Nigeria, MLSCN, lo fi ọrọ naa lede pe awọn awoyanu ni ọpọ awọn ibi ti awọn ṣalabaapade nipinlẹ Ọṣun ti awọn kọlọransi yii ti n ṣayẹwo ẹjẹ fun awọn onibaara wọn.

Bakan naa ni wọn gbe kọkọrọ si ẹnu ọna awọn ibudo mẹrinlelọgbọn, titi digba ti awọn to ni wọn yoo fi ṣe ohun to tọ nibaamu pẹlu alakalẹ ajọ naa.

Gẹgẹ bi James Ogbeche, ẹni to jẹ adari ẹka ayẹwo fun ajọ naa, ṣe sọ fawọn oniroyin, lara awọn ibudo mọkanlelaaadọrun ti wọn ṣabẹwo si kaakiri ipinlẹ Ọṣun ni wọn ti ṣawari awọn ti wọn ti pa yii latari iṣẹ ti ko kunju oṣunwọn ti wọn n ṣe nibẹ.

O ni eeyan kan ko le deede pe ara rẹ ni alayẹwo ẹjẹ lai gba lansẹnsi tabi lai ni ibudo to wa nibaamu pẹlu alakalẹ ofin ajọ naa.

Ogbeche fi kun ọrọ rẹ pe iyalẹnu lo jẹ nigba ti awọn de awọn ilu bii Iwo, Ẹdẹ, Oṣogbo, Ifẹ, Ileṣa, Mọdakẹkẹ, Ijẹbu Jesha ati bẹẹ bẹẹ lọ, tawọn si ri awọn agbegbe ti awọn eeyan yii ti n ṣe ayẹwo ẹjẹ fun awọn alaimokan araalu.

O sọ siwaju pe bi awọn kan ṣe n lo inu yara ti wọn n sun, lawọn mi-in n lo inu ile idana, bẹẹ ni ọpọ n gbe apẹrẹ ẹjẹ (blood sample) sinu ẹrọ amomitutu (fridge) ti wọn n gbe ounjẹ jijẹ pamọ si, eyi to si lewu pupọ.

O ni ojuṣe ajọ naa ni lati ri i daju pe awọn ibudo ti wọn ti n yẹ ẹjẹ awọn araalu wo bojumu, ti esi ti wọn yoo si gba nibẹ yoo jẹ otitọ, ti ko ni i ko idaamu ba awọn eeyan.

O sọ siwaju pe odidi ọjọ marun-un lawọn fi lọ kaakiri awọn ibudo ayẹwo ẹjẹ aladaani, ati pe awọn n pada bọ ki ọdun 2022 too pari lati ṣayewo si awọn ibudo ayẹwo ẹjẹ to jẹ tijọba ipinlẹ Ọṣun.

O rọ awọn araalu lati kiyesara nipa awọn ibi ti wọn aa maa lọ fun ayẹwo ẹjẹ, ki wọn mọ pe abajade ti wọn ba fun wọn le ni ipa to buru tabi eyi to dara lori igbesi aye wọn.

Ninu ọrọ rẹ, Kọmiṣanna feto ilera l’Ọṣun, Dokita Rafiu Isamọtu, sọ pe ijọba ti gbe igbimọ ti yoo ṣiṣẹ tọ igbesẹ awọn ajọ naa lati ri i daju pe awọn kọlọrọsi yii ko tun lọ ṣi awọn ibudo ti wọn ti pa yii pada.

Leave a Reply