Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Awọn ọkunrin mẹrin kan, Jẹmili Ismaila, Amidu Bankọle, Elijah Samson ati Moses Proboye lọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ bayii lori iku agbofinro kan ti orukọ ẹ n jẹ Agada Akoh, ti wọn ni wọn lu pa ni Dalemọ, Sango Ọta, lọjọ kẹtala, oṣu kẹsan-an yii.
Ipinlẹ Kogi la gbọ pe ọlọpaa to doloogbe yii ti n bọ gẹgẹ bi Abimbọla Oyeyẹmi, alukoro ọlọpaa ṣe ṣalaye. O ni ọga rẹ lo tẹle wa lati Idah, nipinlẹ Kogi. Igba ti wọn de Sango ninu mọto wọn ti wọn n gbe bọ ni Jamili Ismaila toun n wa tirela wa mọto tiẹ niwakuwa, to bẹẹ to jẹ diẹ lo ku ko kọlu awọn ọlọpaa yii.
Eyi lo mu awọn agbofinro naa sọkalẹ ninu mọto wọn, ti wọn si kilọ fun Jamili pe ko yee wa iwakuwa.
Ṣugbọn wọn ni niṣe ni Jamili binu, to ni awọn ọlọpaa naa loun ko fẹẹ kọlu toun fi bọ si koto, ti taya mọto oun kan si bẹ. Ibinu naa ni wọn lo jẹ ko pe awọn ọmọ ganfe to wa nitosi lati gbeja oun, n lawọn iyẹn ba mu nnkan ija oriṣiisriṣii jade, ni wọn ba kọju ija sawọn ọlọpaa, agaga Agada to jẹ ọmọọṣẹ, bi wọn ṣe bẹrẹ si i lu u bii ko ku niyẹn.
Alukoro sọ pe nibi ti wọn ti n lu ọlọpaa naa lo daku si, awọn ẹlẹyinju aanu lo sare gbe e lọ sileewoan Jẹnẹra Ọta, ṣugbọn nibi ti wọn ti n tọju rẹ lo dakẹ si.
Awọn ọmọ ganfe to lu u sa lọ nigba ti wọn ri i pe ọlọpaa naa ti daku, ṣugbọn ọwọ pada tẹ awọn mẹrin yii, nigba tawọn ọlọpaa ṣọ wọn daadaa ni wọn ka wọn mọ ibuba wọn.
Mọṣuari ileewosan jẹnẹra Ọta ni wọn gbe oku Agada Akoh si bayii, bẹẹ ni wọn ṣi n wa awọn ọmọ ganfe yooku to sa lọ.