Ọwọ tẹ awọn ọmọ Yahoo mẹẹẹdogun, ọmọ oojọ ni wọn ri mọlẹ laaye

Jamiu Abayọmi

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers, pẹlu iranlọwọ awọn ọdẹ adugbo ti ba awọn afurasi ọmọ Yahoo mejila kan ti wọn ri ọmọ ikoko mọlẹ looyẹ laduugbo Eagle Island, niluu Port Harcourt, ipinlẹ naa, l’Ojọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtalelogun, osu Kẹjọ, ọdun 2023 yii.

ALAROYE gbọ pe awọn kan ni wọn ta awọn agbofinro yii lolobo ti wọn fi tọpasẹ wọn, ki wọn too maa ṣa wọn lọkọọkan-ejeeji tọwọ fi ba gbogbo wọn.

Alaga ikọ ẹṣọ alaabo kan ti wọn n pe ni PLGA, lagbegbe Eagle Island, Victor Ohaji, to fidii iṣẹlẹ naa mulẹ fawọn oniroyin sọ pe lasiko tawọn ọmọkunrin yii n gbẹlẹ ti wọn, si n pọfọ, pogede, payajọ kikankikan lawọn araduugbo ta awọn lolobo, tawọn naa si ke si teṣan ọlọpaa Azikiwe, niluu Port Harcourt, tawọn si jọ tọpasẹ wọn lọ, ṣugbọn  kawọn too debẹ ni wọn ti sa lọ, amọ awọn ri ipa  pe wọn ri nnkan mọlẹ sibẹ.

“Nigba ta a debẹẹ, a gbẹ ibi ti a ṣakiyesi pe wọn ri nnkan mọ, a si ba ọmọ tuntun, to jẹ ọkunrin, nibẹ, lẹsẹkẹsẹ la pe akiyesi awọn ọlọpaa si ohun ti a ri.

“A tọpasẹ wọn lọ, a si n yẹ gbogbo otẹẹli to wa lagbegbe naa wo, titi ti a fi ri wọn, bi wọn ṣe ri wa ni wọn fere ge e, ti a si le wọn mu, a si ri awọn mejeejila mu, at’ọmọ ati awọn afurasi naa ni a fa le ọlọpaa lọwọ”.

Ohaji kadi ọrọ rẹ nilẹ pe ọkan wa ninu awọn afurasi naa ti ko tiẹ ri nnkan ti wọn ṣe naa bii iwa ọdaran, niṣe lo tun n fọnnu pe bi baba oun ba de to jẹ ọga ologun, yoo waa gba awọn silẹ lakolo ọlọpaa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ naa, Grace Iringe-Koko, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe loootọ lọwọ ti ba awọn afurasi ọmọ Yahoo ti wọn ri ọmọ oojọ mọlẹ looyẹ ọhun.

“Loootọ niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, awọn ọlọpaa ati ikọ fijilante lo fọwọ ṣikun ofin mu wọn, a si ti taari iṣelẹ naa lọ si ẹka to n wadii iwa ọdaran fun ẹkunrẹrẹ iwadii. Ni kete ti iwadii ba pari ni wọn yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply