Ọwọ tẹ awọn ọrẹ mẹta yii, ẹya ara oku ni wọn ba lọwọ wọn l’Ekoo 

Adewale Adeoye

Ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ awọn afurasi ọdaran mẹta kan ti wọn ti jingiri ninu tita ẹya ara oku fawọn onibaara wọn kan niluu Eko, wọn si ti n ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Awọn afurasi ọdaran ọhun ni: Ọgbẹni Isah Amohullahi, ẹni ọgbọn ọdun, Abubarkar Isah, ẹni ọdun mejilelọgbọn ati Gbolahan Temidayọ.

ALAROYE gbọ pe ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, lọwọ awọn ọlọpaa ori biriiji Ọtẹdọla, nipinlẹ Eko, tẹ meji ninu wọn lasiko ti wọn wa ninu ọkọ kan. Wọn ba ahọn oku atawọn ẹya ara mi-in lọwọ wọn ninu baagi kekere kan ti wọn gbe e si. Loju-ẹsẹ ti wọn ri ẹya ara oku naa lọwọ wọn ni wọn ti fọwọ ofin mu wọn ju sahaamọ ọlọpaa agbegbe naa.

Lẹyin naa ni wọn lọọ fọwọ ofin mu ẹni kẹta wọn, iyẹn Gbọlahan, ti wọn sọ pe ọwọ rẹ lawọn ti ra a ninu ọja Oyingbo niluu Eko.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, sọ pe awọn afurasi ọdaran meji lọwọ awọn ọlọpaa kọkọ tẹ lagbegbe biriiji Ọtẹdọla, lẹyin tawọn fọrọ wa wọn lẹnu wo daadaa ni wọn jẹwọ pe ọwọ Gbọlahan to n taja ninu ọja igbalode Oyingbo, niluu Eko, lawọn ti lọọ gba a, wọn si ti fọwọ ofin mu oun naa bayii. Gbogbo wọn pata ni wọn ti wa lahaamọ ọlọpaa ipinlẹ Eko.

Alukoro ni awọn maa ṣewadi nipa wọn, awọn si maa foju wọn bale-ẹjọ laipẹ.

 

Leave a Reply